+ -

عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«حَقُّ الْمُسْلِمِ عَلَى الْمُسْلِمِ خَمْسٌ: رَدُّ السَّلَامِ، وَعِيَادَةُ الْمَرِيضِ، وَاتِّبَاعُ الْجَنَائِزِ، وَإِجَابَةُ الدَّعْوَةِ، وَتَشْمِيتُ الْعَاطِسِ».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń sọ pé:
"Etọ Musulumi lori Musulumi miiran márùn-ún ni: Dídá salamọ pada, bibẹ alaarẹ wò, titẹle ìsìnkú, didahun ipepe, ṣiṣadura fun ẹniti ó bá sín".

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye diẹ ninu awọn ẹtọ Musulumi lori Musulumi ẹgbẹ́ rẹ̀, Àkọ́kọ́ nínú àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí ni dídá salamọ padà si ẹniti ó bá salamọ si ọ.
Ẹtọ keji: ṣiṣe abẹwo si alaaarẹ.
Ẹtọ kẹta: Títẹ̀lé ìsìnkú láti ilé rẹ̀ titi de àyè ikirun si oku lara, titi de ibi saare rẹ̀, titi tí wọ́n ó fi sin in.
Ẹtọ kẹrin: Dídáhùn ipepe bí ó bá pè é síbi àpèjẹ ìgbéyàwó àti awọn ǹkan mìíràn.
Ẹtọ karùn-ún: Ṣiṣadura fun ẹniti ó bá sín, iyẹn ni pe kí ó sọ fun un nigba ti ó bá ti sọ pe ALHAMDULILLAH lẹyin sínsín: YARHAMUKALLAH, lẹyin naa ni ẹniti ó sín ó sọ pe: YAHDIKUMULLAHU WA YUSLIHU BAALAKUM.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Titobi Islam nibi fífi ẹtọ rinlẹ laarin awọn Musulumi ati síso okùn ijẹ ọmọ-iya ati okùn ifẹ dáadáa laarin wọn.