عن ابن مسعود رضي الله عنه قال: قال النبي صلى الله عليه وسلم:
«الْجَنَّةُ أَقْرَبُ إِلَى أَحَدِكُمْ مِنْ شِرَاكِ نَعْلِهِ، وَالنَّارُ مِثْلُ ذَلِكَ».

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 6488]
المزيــد ...

Lati ọdọ ọmọ Mas'ud - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé:
"Alujanna súnmọ́ ìkọ̀ọ̀kan nínú yín ju okùn bàtà rẹ̀ lọ, Iná naa sì rí bẹ́ẹ̀".

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6488]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – fún wa niroo pé Alujanna ati Ina súnmọ́ ènìyàn gẹgẹ bi okùn bàtà tó máa n wà lókè ẹsẹ̀ ṣe súnmọ́, nitori pé ó ṣee ṣe kí eniyan ṣe iṣẹ ijọsin kan, kí iṣẹ yii sì mu un rí iyọnu Ọlọhun, yoo sì mu un wọ Alujanna, ó sì ṣee ṣe kó dá ẹṣẹ kan, kí ẹ̀ṣẹ̀ yii sì jẹ́ okunfa fun un tí yoo fi wọ Ina.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ìmúni nífẹ̀ẹ́ láti maa ṣe rere kódà bí ó bá kéré, ati ilenisa kuro nibi ṣiṣe aburu kódà bí ó bá kéré.
  2. kò sí tabi-ṣugbọn fún musulumi nibi pé kí ó kó irankan ati ìbẹ̀rù papọ ninu aye rẹ̀, kí ó sì maa bẹ Ọlọhun Ọba ni gbogbo igba pé kí Ó mú oun duro sinsin lori ododo títí oun ó fi là, tí iṣesi tí oun wà ò fi nii kó itanjẹ bá oun.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (67)