عَنْ سُلَيْمَانَ بْنِ صُرَدٍ رضي الله عنه قَالَ:
كُنْتُ جَالِسًا مَعَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ وَرَجُلاَنِ يَسْتَبَّانِ، فَأَحَدُهُمَا احْمَرَّ وَجْهُهُ، وَانْتَفَخَتْ أَوْدَاجُهُ، فَقَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «إِنِّي لَأَعْلَمُ كَلِمَةً لَوْ قَالَهَا ذَهَبَ عَنْهُ مَا يَجِدُ، لَوْ قَالَ: أَعُوذُ بِاللَّهِ مِنَ الشَّيْطَانِ، ذَهَبَ عَنْهُ مَا يَجِدُ» فَقَالُوا لَهُ: إِنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ: «تَعَوَّذْ بِاللَّهِ مِنَ الشَّيْطَانِ»، فَقَالَ: وَهَلْ بِي جُنُونٌ؟
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 3282]
المزيــد ...
Lati ọdọ Sulaiman ọmọ Suradin - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ bayi pe:
Mo wa lori ijoko pẹlu Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nigbati awọn arakunrin meji nbu arawọn, ojú ọkan nínú àwọn mejeeji pọ́n kankan, bẹẹni iṣan parikẹ rẹ naa ntana jade, bayi ni Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Re máa ba a) sọ pé: "Dajudaju ẹmi mọ gbólóhùn kan, ti o ba le wi i ni, nkan ti nbi ninu yóò sakuro lọdọ rẹ "ti o ba le sọ pé: "mo wa iṣọ lọdọ Ọlọhun nipa aburu èṣù" (Satani), ibinu ti nbi náà yóò lọ ni wọ́n bá sọ fún un pe: dajudaju Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a) sọ pe: "yáa wá isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù" (Satani), Arakunrin náà bá dahun pe: Se weere kọlu mi ni bi?
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3282]
Arakunrin meji njà lọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a), bẹẹ ni oju ọkan ninu awọn mejeeji ti pọ́n koko, bẹẹ ni isan to yipo ọrun rẹ ti ran jáde.
Ni ojisẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) bá sọ pé: Dajudaju emi mọ gbólóhùn kan ti ẹni to nbinu yii bá wí i, ibinu naa yóò sa kuro fun, ti o ba le sọ pé: mo sa di Ọlọhun nibi aburu èṣù (Satani) ẹni ẹkọ ẹni egbe.
Wọ́n sọ fun un pe: Dajudaju Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pe: Wá isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù (Satani).
Ni o ba dahun, o ni: se were ni mi bi?! o le ro pe ẹnikan kò nii wá isọra nipa èṣù (Satani) ayáafi ẹni tí o ba ya were.