عَنْ أَبِي الدَّرْدَاءِ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«أَلاَ أُنَبِّئُكُمْ بِخَيْرِ أَعْمَالِكُمْ، وَأَزْكَاهَا عِنْدَ مَلِيكِكُمْ، وَأَرْفَعِهَا فِي دَرَجَاتِكُمْ وَخَيْرٌ لَكُمْ مِنْ إِنْفَاقِ الذَّهَبِ وَالوَرِقِ، وَخَيْرٌ لَكُمْ مِنْ أَنْ تَلْقَوْا عَدُوَّكُمْ فَتَضْرِبُوا أَعْنَاقَهُمْ وَيَضْرِبُوا أَعْنَاقَكُمْ؟» قَالُوا: بَلَى. قَالَ: «ذِكْرُ اللهِ تَعَالَى».
[صحيح] - [رواه الترمذي وابن ماجه وأحمد] - [سنن الترمذي: 3377]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Dardaa- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Ṣé ki n fun yin ni iro nipa eyi ti o daa julọ ninu awọn iṣẹ yín, ati eyi ti o mọ julọ ninu rẹ lọdọ Oluwa yin, ati eyi ti o ga julọ ninu rẹ ninu awọn ipo yin ti o si loore julọ fun yin ju nina wura ati fadaka lọ, ti o si loore julọ fun yin ju ki ẹ pade ọta yin ki ẹ si ge awọn ọrun wọn ki wọn si ge ọrun yin lọ? Wọn sọ pé: Bẹẹni. O sọ pe: "Iranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-".
[O ni alaafia] - [Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 3377]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- beere lọwọ awọn saabe rẹ pé: .
Njẹ ẹ fẹ ki n fun yin ni iro ki n si kọ yin ni eyi ti o daa julọ ninu awọn iṣẹ yin ati eyi ti o niyi julọ ninu rẹ ati eyi ti o ga julọ ninu rẹ ati eyi ti o mọ julọ ninu rẹ lọdọ Ọlọhun Ọba Olukapa- Alagbara ti O gbọnngbọn-? .
Ti o ga julọ ninu rẹ ninu awọn ipò yin ninu alujanna?
Ti o loore julọ fun yin ju ṣíṣe saara pẹlu wura ati fadaka lọ?
Ati eyi ti o daa julọ fun yin ju ki ẹ pade ọta yin fun ogun lọ, ki ẹ si ge awọn ọrun wọn ki wọn si ge ọrun yin lọ?
Awọn saabe sọ pe: Bẹẹni a fẹ ìyẹn.
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Iranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni gbogbo asiko ati lori gbogbo isẹsi.