+ -

عن أبي هريرة رضي الله عنه
عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فِيمَا يَحْكِي عَنْ رَبِّهِ عَزَّ وَجَلَّ، قَالَ: «أَذْنَبَ عَبْدٌ ذَنْبًا، فَقَالَ: اللَّهُمَّ اغْفِرْ لِي ذَنْبِي، فَقَالَ تَبَارَكَ وَتَعَالَى: أَذْنَبَ عَبْدِي ذَنْبًا، فَعَلِمَ أَنَّ لَهُ رَبًّا يَغْفِرُ الذَّنْبَ، وَيَأْخُذُ بِالذَّنْبِ، ثُمَّ عَادَ فَأَذْنَبَ، فَقَالَ: أَيْ رَبِّ اغْفِرْ لِي ذَنْبِي، فَقَالَ تَبَارَكَ وَتَعَالَى: عَبْدِي أَذْنَبَ ذَنْبًا، فَعَلِمَ أَنَّ لَهُ رَبًّا يَغْفِرُ الذَّنْبَ، وَيَأْخُذُ بِالذَّنْبِ، ثُمَّ عَادَ فَأَذْنَبَ، فَقَالَ: أَيْ رَبِّ اغْفِرْ لِي ذَنْبِي، فَقَالَ تَبَارَكَ وَتَعَالَى: أَذْنَبَ عَبْدِي ذَنْبًا، فَعَلِمَ أَنَّ لَهُ رَبًّا يَغْفِرُ الذَّنْبَ، وَيَأْخُذُ بِالذَّنْبِ، اعْمَلْ مَا شِئْتَ فَقَدْ غَفَرْتُ لَكَ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 2758]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ninu nǹkan ti o gba wa lati ọdọ Olúwa rẹ tí Ó lágbára ti O gbọnngbọn, O sọ pe: “Ẹru mi da ẹṣẹ kan, o wa sọ pé: Irẹ Ọlọhun, fi orí ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun Àlekè-ọla wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, lẹyin naa o tun ṣẹri pada si idi ẹṣẹ, o wa tun sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tun sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, lẹyin naa o tun ṣẹri pada si idi ẹṣẹ, o wa tun sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tun sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, maa ṣe ohun ti o ba fẹ́, mo ti fi ori jin ọ”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 2758]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n gba ẹgbawa láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pe ti ẹrú ba da ẹṣẹ kan, ti o wa sọ pé: Irẹ Ọlọhun, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o wa mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti yoo waa bo o ni àṣírí, ti yoo si ṣe amojukuro fun un, tabi ki O fi ìyà jẹ ẹ lori ẹ, Mo ti fi ori jin in. Lẹ́yìn naa ni o tun tun ẹṣẹ da, o wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o wa mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti yoo waa bo o ni àṣírí, ti yoo si ṣe amojukuro fun un, tabi ki O fi ìyà jẹ ẹ lori ẹ, Mo ti fi ori jin ẹrú Mi. Lẹ́yìn naa ni o tun tun ẹṣẹ da, o wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o wa mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti yoo waa bo o ni àṣírí, ti yoo si ṣe amojukuro fun un, tabi ki O fi ìyà jẹ ẹ lori ẹ, Mo ti fi ori jin ẹrú Mi. Ki o maa ṣe ohun ti o ba fẹ́ lópin ìgbà ti o ba jẹ pe ti o ba ti n da ẹṣẹ naa ni yoo maa fi ẹṣẹ naa sílẹ̀, ti yoo si ká abamọ, ti yoo si pinnu pé oun ko nii pada síbẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ẹ̀mí rẹ maa borí rẹ, yoo tun wa da ẹṣẹ naa padà, lópin ìgbà ti o ba n ṣe báyìí, ti o n da ẹṣẹ, ti o si n ronupiwada, maa fi ori jin in; torí pé ìrònúpìwàdà maa n wó ohun ti o ba ṣáájú rẹ ni.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Gbigbaaye aanu Ọlọhun si awọn ẹru Rẹ, ati pe ẹṣẹ yòówù ki ọmọniyan da, ohunkóhun yòówù ki o ṣe, ti o ba ti ronupiwada, Ọlọhun maa gba ìrònúpìwàdà rẹ.
  2. Ẹni ti o gbagbọ ninu Ọlọhun maa ni ìrètí amojukuro Olúwa rẹ, o si maa paya ìyà Rẹ̀, yoo waa tètè yára lọ ronupiwada, ko si nii tẹsiwaju nibi ẹṣẹ naa.
  3. Májẹ̀mú ironupiwada ti o ni alaafia ni: Jijawọ kuro nibi ẹṣẹ, ati kika abamọ lori ẹ, ati ìpinnu pe èèyàn ko nii pada sibi ẹṣẹ naa mọ. Tí ìrònúpìwàdà naa ba jẹ kúrò nibi awọn àbòsí ti a ṣe fún awọn èèyàn nipa dúkìá, tabi ọmọlúwàbí, tabi ẹ̀mí, o maa ṣe alekun májẹ̀mú kẹrin, oun naa ni: Bíbọ́ kuro lọwọ ẹni tí ó ni ẹtọ, tabi fifun un ni ẹtọ rẹ.
  4. Pataki imọ nipa Ọlọhun, eyi ti yoo sọ ẹrú di onimimọ nipa awọn alamọri ẹsin rẹ, yoo wa maa ronupiwada nígbàkúùgbà ti o ba ti ṣe àṣìṣe, ko nii sọreti nu, ko si nii tẹsiwaju.