+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«أَلَا أَدُلُّكُمْ عَلَى مَا يَمْحُو اللهُ بِهِ الْخَطَايَا، وَيَرْفَعُ بِهِ الدَّرَجَاتِ؟» قَالُوا بَلَى يَا رَسُولَ اللهِ قَالَ: «إِسْبَاغُ الْوُضُوءِ عَلَى الْمَكَارِهِ، وَكَثْرَةُ الْخُطَا إِلَى الْمَسَاجِدِ، وَانْتِظَارُ الصَّلَاةِ بَعْدَ الصَّلَاةِ، فَذَلِكُمُ الرِّبَاطُ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 251]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Ṣé ki n tọka yin si nnkan ti Ọlọhun fi maa n pa awọn àṣìṣe rẹ, ti O si fi maa n gbe awọn ipo ga?" Wọn sọ pe bẹẹni irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: "Ṣíṣe aluwala ni pípé lori ìnira, ati gbigbe igbẹsẹ pupọ lọ si mọsalasi, ati rireti irun lẹyin irun, ìyẹn ni ida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú".

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 251]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bi awọn saabe rẹ leere pe ṣe wọn fẹ ki oun tọka wọn si awọn iṣẹ ti o maa jẹ okunfa aforijin awọn ẹṣẹ, ati iparẹ rẹ kuro ninu awọn iwe awọn mọlaika ti wọn n kọ iṣẹ, ati gíga awọn ipò ninu alujanna?
Awọn saabe sọ pe: Bẹẹni a fẹ ìyẹn. O sọ pe:
Akọkọ: Kikari ati pipe aluwala lori inira; gẹgẹ bii otutu, ati kíkéré omi, ati inira ara, ati omi gbigbona.
Ikeji: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ igbesẹ- oun ni nnkan ti o wa laaarin ẹsẹ mejeeji- lọ si awọn mọsalasi latara jijina ilé, ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ pipaara.
Ikẹta: Rireti asiko irun, ati sisopọ ọkan mọ ọn, ati ìgbáradì fun un, ati jijokoo sinu mọsalasi fun ireti janmọọn, ti o ba ti ki i ki o maa reti irun miiran ni aaye ti o ti kirun.
Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju awọn àlámọ̀rí yii gan-an ni dida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú; nitori pe o maa n kọdi awọn oju ọna èṣù lọ sọ́dọ̀ ẹmi, o si maa n bori ifẹ inu, ti o maa kọ fun un kuro nibi gbigba awọn royiroyi wọle, ti ijọ Ọlọhun fi maa bori awọn ọmọ ogun èṣù pẹlu rẹ; ìyẹn ni ijagun soju ọna Ọlọhun ti o tobi julọ, o waa wa ni ipo dida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú ọ̀tá.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Pataki sisọ irun janmọọn ninu mọsalasi ati ifiye si awọn irun àti ṣíṣàì jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ níyà kúrò nibẹ.
  2. Didaa agbekalẹ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati mimu awọn saabe rẹ jẹ̀rán nigba ti o bẹ̀rẹ̀ fun wọn pẹlu ẹsan ti o tobi ni ọna ibeere, ati pe ọna yii wa ninu awọn ọna ikọnilẹkọọ.
  3. Anfaani ti o n bẹ nibi ṣíṣe àfihàn ọ̀rọ̀ pẹlu ìbéèrè ati idahun ni: Ki ọrọ le wọni lọ́kàn gan-an nítorí kiko àìṣekedere pọ̀ mọ́ ìṣekedere.
  4. An-nawawi- ki Ọlọhun kẹ ẹ- sọ pe: FAZAALIKUMU-R-RIBAAT n túmọ̀ si: Ribaat ti a fẹ́, ipilẹ ribaat si ni ki èèyàn di nǹkan mú ṣinṣin, bii ìgbà tí o de ẹ̀mí ara rẹ mọ́lẹ̀ fun itẹle aṣẹ yii, wọn sọ pé: Òun ni o daa julọ ninu awọn ribaat gẹgẹ bi wọn ṣe sọ pe: Ijagun soju ọna Ọlọhun ni jija ẹ̀mí lógun, o si tun le túmọ̀ si ribaat ti o rọrun, o n túmọ̀ si pe: O wa ninu awọn oríṣiríṣi ribaat.
  5. Wọn paara gbolohun "Ar-Ribaat" wọn si so Alif ati Laam mọ́ ọn; ìyẹn jẹ igbetobi fun àlámọ̀rí awọn iṣẹ yìí.