عَنْ حَارِثَةَ بْنِ وَهْبٍ الخُزَاعِيِّ رضي الله عنه قَالَ: سَمِعْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«أَلاَ أُخْبِرُكُمْ بِأَهْلِ الجَنَّةِ؟ كُلُّ ضَعِيفٍ مُتَضَعِّفٍ، لَوْ أَقْسَمَ عَلَى اللَّهِ لَأَبَرَّهُ، أَلاَ أُخْبِرُكُمْ بِأَهْلِ النَّارِ: كُلُّ عُتُلٍّ جَوَّاظٍ مُسْتَكْبِرٍ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 4918]
المزيــد ...
Lati ọdọ Haarithah ọmọ Wahbi Al-Khuzaa'iyy - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ pe: mo gbọ Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - tí ń sọ bayi pe:
"Ẹ jẹ kín fún yín ní ìró nipa awọn ẹni Alujanna? gbogbo ọlẹ ti ko lágbára rara, ti o ba búra iroro nkan síwaju Ọlọhun, Ọlọhun yóò sọ ọ di daada, ẹ jẹ kí nfun yin ni iro nipa awọn ẹni iná: gbogbo ẹni ti o le koko, ti nrin tanlu tanlu, oni moto moto".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 4918]
Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro apakan awọn iroyin awọn ẹni Alujanna (ọgbà idẹra) ati awọn ẹni ina.
Awọn ti wọn pọ̀jù nínú ẹni Alujanna awọn ni: "gbogbo ọlẹ ti kò lágbára rara" itumọ rẹ nipe: ẹni tí o ntẹriba ti o si njirẹbẹ fún Ọlọhun ti o ga jùlọ, ti o rẹ raa rẹ fun Un, debiipe apakan awọn eniyan wọn npe e ni ọlẹ, wọn nyẹpẹrẹ rẹ̀, ẹni ti o yẹpẹrẹ araa rẹ̀ fun Ọlọhun yii, ti o ba fi Allah (Ọlọhun) bura ni enití n rokan si oore Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, Allah yoo sọ di daada, yoo si sọ ohun ti o bura le lori di ootọ, yoo si da lohun ohun ti o beere ati adua rẹ.
Awọn ti wọn pọju ninu awọn ẹni iná ni gbogbo "oni iwa to le koko" ohun ni onibinu, ọlọkan líle koko, alajangbila, tabi oni iwa ibajẹ (alaburu) ti kii tẹriba fún daada, "onigirimọkai" ohun ni oni moto moto, Alajẹju (okuonjẹ), ẹni tori gbàngbà, ti nrin irin tanku taloku (irin akọ) oniwa buruku, "oni moto moto" pẹlu aigba ododo wọle, ati ifoju yẹpẹrẹ wo awọn elomiran.