عن جابر رضي الله عنه قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«أَفْضَلُ الذِّكْرِ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، وَأَفْضَلُ الدُّعَاءِ: الْحَمْدُ لِلهِ».
[حسن] - [رواه الترمذي والنسائي في الكبرى وابن ماجه] - [سنن الترمذي: 3383]
المزيــد ...
Lati ọdọ Jabir - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí n sọ pé:
"Eyi tó lọ́lá jùlọ ninu awọn iranti Ọlọhun ni gbolohun: LAA ILAAHA ILLALLOOH, eyi tó sì lọ́lá jùlọ ninu awọn adura ni gbolohun: ALHAMDULILLAH".
[O daa] - [Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa ninu al-Kubrọ, ati Ibnu Maajah] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 3383]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fún wa pé iranti Ọlọhun tó lọ́lá jùlọ ni: "LAA ILAAHA ILLALLOOH" itumọ rẹ̀ ni pé kò sí nkankan tí a gbọdọ̀ jọsin fun pẹlu ododo ayafi Ọlọhun Allah, ati pé adura tó lọ́lá jùlọ ni ALHAMDULILLAH; iyẹn ni pé a n fi rinlẹ̀ pé dajudaju Allahu ni Oluṣedẹra fún wa, Oun ni O sì lẹtọọ si iroyin tó pé, tó sì dara julọ.