عن سَمُرَة بن جندبٍ رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«أَحَبُّ الْكَلَامِ إِلَى اللهِ أَرْبَعٌ: سُبْحَانَ اللهِ، وَالْحَمْدُ لِلهِ، وَلَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، وَاللهُ أَكْبَرُ، لَا يَضُرُّكَ بِأَيِّهِنَّ بَدَأْتَ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2137]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Samurah ọmọ Jundub- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
Ọ̀rọ̀ ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ mẹrin ni: SUBHAANALLAH, ati ALHAMDULILLAAH, ati LAA ILAAHA ILLALLOOH, ati ALLAHU AKBAR, èyíkéyìí ti o ba wù ọ ni o le fi bẹ̀rẹ̀ nínú wọn”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2137]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ọ̀rọ̀ ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ mẹ́rin ni:
SUBHAANALLAH: O n túmọ̀ sí fifọ Ọlọhun mọ́ kuro nibi gbogbo adinku.
ALHAMDULILLAAH: Oun ni fífi pípé ròyìn Ọlọhun pẹlu ìfẹ́ Rẹ̀ ati gbigbe E tobi.
LAA ILAAHA ILLALLOOH: Ìtumọ̀ rẹ ni: Ko si ẹni ti a le maa jọ́sìn fun ni ododo ayafi Ọlọhun.
ALLAHU AKBAR: Ìtumọ̀ rẹ ni: O gbọnngbọn, O si tobi, O si ni agbara ju gbogbo nnkan lọ.
Ati pe ọla rẹ ati rírí ẹsan rẹ, ko beere fun títò ó tẹle ara wọn ti a ba n pe wọn jáde lẹ́nu.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Irọrun sharia, latara pe o le bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èyíkéyìí tí o ba fẹ ninu awọn gbolohun naa.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (67)