+ -

عن جَرِيْر بنِ عبدِ الله رضي الله عنه قال:
كُنَّا عِنْدَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَنَظَرَ إِلَى الْقَمَرِ لَيْلَةً -يَعْنِي الْبَدْرَ- فَقَالَ: «إِنَّكُمْ سَتَرَوْنَ رَبَّكُمْ كَمَا تَرَوْنَ هَذَا الْقَمَرَ، لَا تُضَامُونَ فِي رُؤْيَتِهِ، فَإِنِ اسْتَطَعْتُمْ أَنْ لَا تُغْلَبُوا عَلَى صَلَاةٍ قَبْلَ طُلُوعِ الشَّمْسِ وَقَبْلَ غُرُوبِهَا فَافْعَلُوا» ثُمَّ قَرَأَ: «{وَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ قَبْلَ طُلُوعِ الشَّمْسِ وَقَبْلَ الْغُرُوبِ}»

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Jeriir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
A wa lọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa wo òṣùpá ni alẹ ọjọ́ kan- o n túmọ̀ si òṣùpá ọjọ kẹrinla- o wa sọ pe: "Dajudaju ẹ maa ri Oluwa yin gẹgẹ bi ẹ ṣe n ri òṣùpá yìí, ẹ o nii ri inira nibi riri rẹ, ti ẹ ba ni ikapa ki wọn maa kọdi yin kuro nibi irun ṣíwájú yiyọ oorun ati ṣíwájú wiwọ rẹ, ki ẹ yaa ṣe bẹẹ" lẹyin naa o ka:"(Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa Rẹ ṣíwájú yíyọ òòrùn àti wíwọ̀ (rẹ̀).)"

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Awọn saabe wa pẹlu Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni alẹ ọjọ kan, o wa wo òṣùpá- ni ale ọjọ kẹrinla-, o wa sọ pe: Dajudaju awọn olugbagbọ maa ri Oluwa wọn ni ti paapaa pẹlu oju laisi iruju, ati pe wọn ko nii fún papọ mọ́ra wọn, wahala tabi inira ko nii ṣẹlẹ̀ si wọn nibi riri Rẹ- Ọba ti ọla Rẹ ga-. Lẹyin naa, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ti ẹ ba ni ikapa lati ge awọn okunfa ti o le yi yin kuro nibi irun asunbaa ati irun Asr, ki ẹ yaa ṣe bẹẹ, ki ẹ si mu mejeeji wa ni pipe ni asiko mejeeji ni janmọọn, dajudaju ìyẹn wa ninu awọn okunfa wiwo oju Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn, Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ka aaya naa: (Wa sabbih bihamdi Robbika qobla tuluu'ish shamsi wa qoblal guruub)

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Iro idunnu fun oni igbagbọ pẹlu riri Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ninu alujanna.
  2. Ninu awọn ọna ipepe ni: Ikanpamọ ati ifanilojumọra ati mimu awọn apẹẹrẹ wa.