عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«مَنْ أَنْظَرَ مُعْسِرًا، أَوْ وَضَعَ لَهُ، أَظَلَّهُ اللهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ تَحْتَ ظِلِّ عَرْشِهِ يَوْمَ لَا ظِلَّ إِلَّا ظِلُّهُ».
[صحيح] - [رواه الترمذي وأحمد] - [سنن الترمذي: 1306]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
“Ẹni ti o ba lọ onigbese lára, tabi ti o ba a din in ku tabi ki o ni ki o ma san an mọ́, Ọlọhun maa fi i sábẹ́ ibòji Ìtẹ́-ọlá Rẹ̀ ni Ọjọ́ Àjíǹde, ni ọjọ́ ti ko nii si ibòji kankan àyàfi ibòji Rẹ̀”.
[O ni alaafia] - [Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 1306]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé ẹni tí o ba lọ onigbese lára, tabi ti o ba a din gbese rẹ ku, ẹsan rẹ ni pe: Ọlọhun maa fi i sábẹ́ ibòji Itẹ-ọla Rẹ̀ ni Ọjọ́ Àjíǹde ti oorun maa sunmọ orí àwọn ẹrú ti ooru rẹ si maa lágbára, Ẹni kankan ko nii ri ibòji àyàfi ẹni tí Ọlọhun ba fi si abẹ ibòji.