عَنْ أَبَي قَتَادَةَ رضي الله عنه أنَّهُ طَلَبَ غَرِيمًا لَهُ، فَتَوَارَى عَنْهُ ثُمَّ وَجَدَهُ، فَقَالَ: إِنِّي مُعْسِرٌ، فَقَالَ: آللَّهِ؟ قَالَ: آللَّهِ؟ قَالَ: فَإِنِّي سَمِعْتُ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«مَنْ سَرَّهُ أَنْ يُنْجِيَهُ اللهُ مِنْ كُرَبِ يَوْمِ الْقِيَامَةِ فَلْيُنَفِّسْ عَنْ مُعْسِرٍ أَوْ يَضَعْ عَنْهُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 1563]
المزيــد ...
Láti ọdọ bàbá Qataada - ki Ọlọhun yọnu si - o ni oun wá ẹni tó jẹ oun lówó, o wa fi ara pamọ fún òun lẹyìn náà òun padà rí i, ni o wa sọ pé: oun wa ninu ìṣòro lati sanwo rẹ, ni o wá ṣọ pe: se o le fi orukọ Ọlọhun búra? o sọ pe: se o le fi orukọ Ọlọhun búra? o sọ pé: dájúdájú emi gbọ ti òjíṣẹ Ọlọhun (ki ike Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ti nsọ pe:
"Ẹnikẹni ti o bá dun mọ ki Ọlọhun koo yọ nibi ìbànújẹ ọjọ igbende ko yaa se ìgbà láàyè fún ẹni tí ara ni lati san gbèsè tabi ko yá yaafi gbèsè náà fun".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 1563]
Abu Qotaada ará Madinah ki Ọlọhun yonu si nsọ nipa onígbèsè rẹ kan ti n fara pamọ́ fún, ni o ba ri, ni onígbèsè náà bá sọ pé: "ará o dé mi, mi o ti ni owó lati fi sàn gbèse rẹ.
Ní Abu Qotaada ki Ọlohun yọnu si bá ní kí ofi orúkọ Ọlọhun búra pé kò sí òwò lọwọ oun?
Ni o ba fi orukọ Ọlọhun búra fún pe ootọ ní òun sọ,
Ni Abu Qotaada ki Ọlọhun yọnu si bá sọ pé òun gbọ ti Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati Ọlá Rẹ má ba) ti nsọ pe:
Ẹní tí yóò bá dún mọ ki Ọlọhun sakoyọ rẹ ni bi ìbànújẹ ọjọ igbende àti ilékoko ọjọ náà ati awọn ìbẹrù rẹ ko yá se idẹra fún ẹni tí kò lágbára láti san gbèse rẹ lasiko, pẹlú pe ko fi kun àsìkò ṣiṣan tábì ki o dín kù tabi ki o bùn ní gbogbo ẹ.