عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«مَنْ صَامَ رَمَضَانَ إِيمَانًا وَاحْتِسَابًا غُفِرَ لَهُ مَا تَقَدَّمَ مِنْ ذَنْبِهِ»
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 38]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹni tí ó bá gba aawẹ Ramadan ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹsẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 38]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni tí o ba gba aawẹ oṣù Ramadan ni ti igbagbọ ninu Ọlọhun, ati gbigba ìjẹ-ọran-anyan aawẹ ni ododo, ati ohun ti Ọlọhun pèsè kalẹ fun awọn alaawẹ bii ẹsan ti o pọ̀, ni ẹni tí n gbèrò ojú-rere Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ti kii ṣe ti ṣekarimi tabi ṣekagbọmi, wọn maa fi orí àwọn ẹṣẹ rẹ ti o ti kọjá jin in.