+ -

عن أَبِي مُوسَى الأَشْعَرِيِّ رضي الله عنه: أَنَّ رَسُولَ اللهِ صلى الله عليه وسلم قَالَ:
«مَنْ صَلَّى ‌الْبَرْدَيْنِ دَخَلَ الْجَنَّةَ»

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 574]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash'ariy- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Ẹni ti o ba kirun tutu mejeeji o maa wọ alujanna"

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 574]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe wa lojukokoro lori akolekan irun tutu mejeeji, awọn mejeeji ni irun Asunbaa ati irun Alaasari, o si fun wa ni iro idunnu pe ẹni ti o ba mu mejeeji wa pẹlu ẹtọ mejeeji ninu asiko ati ni janmọọn ati eyi ti o yàtọ̀ si ìyẹn, mejeeji maa jẹ okunfa wiwọ alujanna rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti o n bẹ fun àbójútó irun alufajari ati alaasari; nitori pe alufajari maa n waye lasiko igbadun oorun, ti alaasari si maa n waye ni asiko iko-airoju ọmọniyan pẹlu iṣẹ rẹ, ẹni ti o ba n bójú tó mejeeji, o sunmọ ki o rọrun fun un lati bójú tó awọn irun yoku.
  2. Wọn sọ irun alufajari ati alaasari ni tutu mejeeji; nitori pe irun alufajari otutu oru n bẹ nibẹ, ti otutu ọsan si n bẹ nibi irun alaasari, bi o ti lẹ jẹ pe asiko ti o maa n waye maa n gbóná, ṣùgbọ́n o maa n fuyẹ ju ìgbóná asiko ti o ṣíwájú rẹ lọ, tabi ki sisọ wọn bẹẹ jẹ lábẹ́ fifi ọ̀rọ̀ kan borí ọ̀kan ni, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n sọ pe: Al-qomoraan fun oorun ati òṣùpá.