عن جُندب بن عبد الله القَسْرِِي رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«مَنْ صَلَّى صَلَاةَ الصُّبْحِ فَهُوَ فِي ذِمَّةِ اللهِ، فَلَا يَطْلُبَنَّكُمُ اللهُ مِنْ ذِمَّتِهِ بِشَيْءٍ، فَإِنَّهُ مَنْ يَطْلُبْهُ مِنْ ذِمَّتِهِ بِشَيْءٍ يُدْرِكْهُ، ثُمَّ يَكُبَّهُ عَلَى وَجْهِهِ فِي نَارِ جَهَنَّمَ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 657]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Jundub ọmọ Abdullahi Al-Qasriy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹni tí ó bá ki irun asunbaa, onítọ̀hún ti wa nínú ààbò Ọlọhun, nítorí náà ẹ ṣọ́ra ki Ọlọhun ma baa bi yin leere nǹkan kan ninu ààbò Rẹ̀; torí ẹni ti Ọlọhun ba bi leere nǹkan kan nínú ààbò Rẹ̀, yoo gba ẹsan lara rẹ, yoo si da ojú rẹ bo ilẹ̀ ninu ina Jahannama”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 657]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí o ba ki irun alufajari ti wa ninu iṣọ Ọlọhun ati ààbò Rẹ, yoo maa da aabo bo o, yoo si maa ṣẹ́gun fun un.
Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣọ wa lara kúrò nibi títú àdéhùn naa ati biba a jẹ́, yálà pẹlu gbigbe irun alufajari ju silẹ ni, tabi ìkọlù ẹni ti n ki i, ẹni tí ó bá ṣe iyẹn ti ba ààbò yii jẹ́, o si ni ẹtọ si àdéhùn ìjìyà ti o le koko pẹ̀lú pe ki Ọlọhun bi i leere nípa ohun tí o ṣe àṣeètó nibẹ nibi ẹtọ Rẹ, ẹni tí Ọlọhun ba bi léèrè, yoo gba ẹsan lara rẹ, lẹ́yìn náà yoo da oju rẹ bo ilẹ̀ ninu iná.