عن أبي هريرة رضي الله عنه عن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«مَنْ كَانَ يُؤْمِنُ بِاللهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ فَلْيَقُلْ خَيْرًا أَوْ لِيَصْمُتْ، وَمَنْ كَانَ يُؤْمِنُ بِاللهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ فَلْيُكْرِمْ جَارَهُ، وَمَنْ كَانَ يُؤْمِنُ بِاللهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ فَلْيُكْرِمْ ضَيْفَهُ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 47]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé:
“Ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹyìn, ki o maa sọ dáadáa tabi ki o dakẹ, ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ki o yaa maa ṣe apọnle aládùúgbò rẹ, ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹyìn, ki o maa ṣe apọnle àlejò rẹ”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 47]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe ti ẹrú ti o gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ti o maa padà si ti wọn si maa san an ni ẹsan iṣẹ rẹ nibẹ, igbagbọ rẹ maa ṣe e ni ojúkòkòrò lori ṣíṣe àwọn nǹkan yii:
Akọkọ: Ọ̀rọ̀ dáadáa: Bii gbólóhùn SUBHAANALLAH ati LAA ILAAHA ILLALLOOH, ati pipaṣẹ dáadáa, ati kikọ ibajẹ, ati ṣíṣe àtúnṣe láàárín àwọn èèyàn, ti ko ba wa ṣe e, ki o yaa dakẹ, ki o si ma fi suta kan èèyàn, ki o si ṣọ ahọ́n rẹ.
Ìkejì: Ṣíṣe apọnle aládùúgbò: Pẹ̀lú ṣíṣe dáadáa si wọn, ati ki èèyàn si ma fi suta kan an.
Ikẹta: Ṣíṣe apọnle àlejò ti n bọ láti ṣe abẹwo rẹ: Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dáadáa, ati fífún un ní oúnjẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.