عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«أَقْرَبُ مَا يَكُونُ الْعَبْدُ مِنْ رَبِّهِ وَهُوَ سَاجِدٌ، فَأَكْثِرُوا الدُّعَاءَ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 482]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni ìgbà ti o ba wa ni iforikanlẹ, ki ẹ yaa maa ṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 482]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni ìgbà ti o ba wa ni iforikanlẹ; ìyẹn ni pe ẹni ti n kirun maa fi ibi ti o ga ju ti o si niyi ju ninu ara rẹ lé ilẹ̀ ni ti ìtẹríba ati irẹlẹ fun Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ti o si wa ni iforikanlẹ.
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti wa pàṣẹ ṣíṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni iforikanlẹ, o maa wa kójọ ninu ìyẹn irẹlẹ fun Ọlọhun pẹlu ọ̀rọ̀ ati ìṣe.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Itẹle àṣẹ Ọlọhun maa n le ẹrú kún ni isunmọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
  2. A fẹ́ ki a maa ṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni iforikanlẹ; torí pé ó wa ninu awọn ààyè gbigba adua.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (67)