عَنْ عُبَادَةَ بْنِ الصَّامِتِ رضي الله عنه أَنَّ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«لَا صَلَاةَ لِمَنْ لَمْ يَقْرَأْ بِفَاتِحَةِ الكِتَابِ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 756]
المزيــد ...

Lati ọdọ Ubaadah ọmọ Saamit - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Ko si irun fun ẹni ti ko ba ka Faatiha».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 756]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju irun o le ni alaafia ayaafi pẹlu kika suuratul Faatiha, o si jẹ origun kan ninu awọn origun irun nibi gbogbo rakaha.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Nkankan o le dipo kika Faatiha yatọ si i pẹlu nini ikapa lati ka a.
  2. Bibajẹ rakaha eleyii ti wọn o ka Faatiha ninu rẹ, lati ọdọ ẹni ti o finu-findọ ṣe e, ati alaimọkan ati onigbagbe; nitori pe dajudaju origun ni i, ati pe awọn origun o lee bọ lailai.
  3. Kika Faatiha o maa bọ fun ero ẹyin nigba ti o ba ba imaamu ni rukuu.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (54)