عن سالم بن أبي الجَعْدِ قال: قال رجل: ليتني صَلَّيتُ فاسترحْتُ، فكأنّهم عابُوا ذلك عليه، فقال: سمعتُ رسولَ الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«يا بلالُ، أقِمِ الصَّلاةَ، أرِحْنا بها».
[صحيح] - [رواه أبو داود] - [سنن أبي داود: 4985]
المزيــد ...
Lati ọdọ Saalim ọmọ Abul Jahd, o sọ pe: Arakunrin kan sọ pé: Ìbá ṣe pé mo ti kírun kí n sì sinmi, bí ẹni pé wọ́n dá a lẹ́bi fún ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
“Irẹ Bilal, gbe irun duro, fun wa ni ìsinmi pẹlu rẹ”.
[O ni alaafia] - [Abu Daud ni o gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 4985]
Arakunrin kan ninu awọn saabe sọ pe: Ìbá ṣe pé mo ti kírun ni, kí n sì sinmi, ó dà bíi pé àwọn tó wà láyìíká rẹ̀ dá a lẹ́bi lórí ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: Irẹ Bilal! Pe irun, ki o si gbe e dúró; ki a le sinmi pẹlu rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ fun nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu biba Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọrọ ni jẹẹjẹ, ati isinmi fun ẹmi ati ọkan.