+ -

عن عمر بن الخطاب رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«إِذَا قَالَ الْمُؤَذِّنُ: اللهُ أَكْبَرُ اللهُ أَكْبَرُ، فَقَالَ أَحَدُكُمُ: اللهُ أَكْبَرُ اللهُ أَكْبَرُ، ثُمَّ قَالَ: أَشْهَدُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، قَالَ: أَشْهَدُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، ثُمَّ قَالَ: أَشْهَدُ أَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللهِ، قَالَ: أَشْهَدُ أَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللهِ، ثُمَّ قَالَ: حَيَّ عَلَى الصَّلَاةِ، قَالَ: لَا حَوْلَ وَلَا قُوَّةَ إِلَّا بِاللهِ، ثُمَّ قَالَ: حَيَّ عَلَى الْفَلَاحِ، قَالَ: لَا حَوْلَ وَلَا قُوَّةَ إِلَّا بِاللهِ، ثُمَّ قَالَ: اللهُ أَكْبَرُ اللهُ أَكْبَرُ، قَالَ: اللهُ أَكْبَرُ اللهُ أَكْبَرُ، ثُمَّ قَالَ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، قَالَ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ مِنْ قَلْبِهِ دَخَلَ الْجَنَّةَ».

[صحيح] - [رواه مسلم]
المزيــد ...

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
«Ti oluperun ba sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, ti ẹnikẹni ninu yin naa wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Hayya‘ala sọlaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Hayya‘alal falaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Laa illaha illā Allāhu, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa illaha illā Allāhu lati inu ọkan rẹ wa yio wọ aljanna».

O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Irun pipe ni fifi mọ awọn eeyan wiwọle asiko irun, ati pe awọn gbolohun irun pipe jẹ awọn gbolohun ti wọn ko adisọkan igbagbọ sinu.
Ati pe ninu hadīth yii Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye nkan ti wọn ṣe ni ofin nigba ti a ba n gbọ ipe irun, oun naa ni ki ẹni ti n gbọ o maa sọ gẹgẹ bi oluperun ṣe n sọ, nigba ti o ba sọ pe "Allāhu Akbar" ẹni ti o n gbọ naa maa sọ pe: "Allāhu Akbar", bayii ni yio ṣe maa lọ; ayaafi nigba ti oluperun ba sọ pe "ayya‘ala sọlaah", "ayya‘alal falaah", nigba naa ẹni ti n gbọ maa sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh".
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - si tun ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba paara nkan ti oluperun n wi ni ti imọkanga lati inu ọkan rẹ yio wọ alujanna.
Itumọ awọn gbolohun irun pipe ni: "Allāhu Akbar": Itumọ rẹ ni pe dajudaju Oun mimọ fun Un ni O tobi julọ, Oun ni o si tun gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ.
"Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu ": Itumọ rẹ ni pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu.
"Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah": Itumọ rẹ ni pe mo n fi rinlẹ mo si tun n jẹrii pẹlu ahọn mi ati ọkan mi pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn ran an ni'ṣẹ, ti itẹle e si jẹ dandan.
"Hayya‘ala sọlaah", itumọ rẹ ni pe ẹ wa lọ ki irun, ati pe gbogbo olugbọ yio sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh", itumọ rẹ ni pe ko si ète kankan lati la kuro nibi awọn nkan ti maa n dena titẹle aṣẹ, kò sì tun si agbara lati ṣe e, bẹẹ ni ko si ikapa lori ikankan ninu awọn nkan wọnyii ayaafi pẹlu kongẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
"Hayya‘alal falaah", itumọ rẹ ni pe ẹ wa sibi okunfa ọla, oun naa ni jijere pẹlu alujanna ati lila kuro nibi ina.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti o wa fun imaa fesi fun oluperun pẹlu sisọ iru nkan ti o n sọ, ayaafi nibi hayya‘ala mejeeji (hayya‘ala solaah ati hayya‘alal falaah), nigba naa yio sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh".