+ -

عَنْ ‌عَبْدِ اللهِ بْنِ عَمْرِو بْنِ الْعَاصِ رضي الله عنها أَنَّهُ سَمِعَ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«إِذَا سَمِعْتُمُ الْمُؤَذِّنَ فَقُولُوا مِثْلَ مَا يَقُولُ، ثُمَّ صَلُّوا عَلَيَّ، فَإِنَّهُ مَنْ صَلَّى عَلَيَّ صَلَاةً صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ بِهَا عَشْرًا، ثُمَّ سَلُوا اللهَ لِيَ الْوَسِيلَةَ، فَإِنَّهَا مَنْزِلَةٌ فِي الْجَنَّةِ، لَا تَنْبَغِي إِلَّا لِعَبْدٍ مِنْ عِبَادِ اللهِ، وَأَرْجُو أَنْ أَكُونَ أَنَا هُوَ، فَمَنْ سَأَلَ لِيَ الْوَسِيلَةَ حَلَّتْ لَهُ الشَّفَاعَةُ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 384]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amru ọmọ al-‘Aas – ki Ọlọhun yọnu si i – dajudaju o gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe:
«Ti ẹ ba ti gbọ oluperun ki ẹ yaa maa sọ gẹgẹ bi o ṣe n sọ, lẹyin naa ki ẹ wa ṣe asalaatu fun mi, torí pé dajudaju ẹni ti o ba ṣe asalaatu kan fun mi Ọlọhun a fi ṣe mewaa fun un, lẹyin naa ki ẹ beere al-Wasiilah fun mi lọdọ Ọlọhun, ati pe dajudaju oun ni ipo kan ninu al-jannah, ti ko si lẹtọọ ayaafi fun ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun, mo si fẹ ki o jẹ emi, nitori naa ẹni ti o ba beere al-Wasiilah fun mi iṣipẹ ti di ẹtọ fun un».

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 384]

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – juwe ẹni ti o ba gbọ oluperun lọ sibi pe ki o maa sọ tẹle e nǹkan ti o ba n wi, nitori naa yio maa sọ iru ọrọ rẹ (oluperun), yatọ si Hayya‘ala mejeeji (Hayya‘alas sọlaah ati Hayya‘alal falaah), yio sọ lẹyin mejeeji pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa yio ṣe asalaatu fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ti o ba pari irun pipe, torí pé dajudaju ẹni ti o ba ṣe asalaatu kan Ọlọhun a titori rẹ ṣe asalaatu mẹwaa fun un, ati pe itumọ asalaatu Ọlọhun fun ẹru Rẹ ni: Ẹyin Rẹ fun ẹru Rẹ lọdọ awọn malaaika.
Lẹyin naa ni o wa paṣẹ pẹlu bibi Ọlọhun leere al-Wasiilah fun oun– ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe oun (al-Wasiilah) naa ni ipo kan ninu al-jannah, ati pe oun lo ga jùlọ ninu rẹ, ko si lẹtọọ bẹẹ ni ko rọrun ayaafi fun ọkan ninu gbogbo awọn ẹru Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ti mo si n tanmọọn ki n jẹ ẹni naa, ati pe o sọ iyẹn – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni ti itẹriba; torí pé dajudaju ti ipo giga yẹn o ba nii wa ayaafi fun ẹnikan, ko wa si ẹni ti o lẹ jẹ ẹnikan yẹn ayaafi oun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -; torí pé oun ni o lọla julọ ninu awọn ẹda.
Lẹyin naa o – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe adua al-Wasiilah fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – iṣipẹ rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – a jẹ tiẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣenilojukokoro lori ijẹpe oluperun (sisọ gẹgẹ bi oluperun ṣe sọ).
  2. Ọla ti n bẹ fun ṣiṣe asalaatu fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ijẹpe oluperun (sisọ gẹgẹ bi oluperun ṣe sọ).
  3. Ṣiṣenilojukokoro lori bibeere al-Wasiilah fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ṣiṣe asalaatu fun un.
  4. Alaye itumọ al-Wasiilah, ati giga ipo rẹ, latari pe ko lẹtọọ ayaafi fun ẹru kan.
  5. Alaye ọla Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – latari pe wọn ṣe ipo ti o ga yẹn ni ẹsa fun un.
  6. Ẹni ti o ba beere al-Wasiilah ni ọwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fún Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – iṣipẹ rẹ (Anabi) ti di ẹtọ fun un.
  7. Alaye itẹriba rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – latari pe o wa lati ọdọ awọn ijọ rẹ ki wọn ṣe adua fun un pẹlu ipo yẹn, toun ti pe dajudaju ti ẹ naa ni yio jẹ.
  8. Gbigbaaye ọla Ọlọhun ati ikẹ Rẹ, nitori naa iṣẹ rere kan ilọpo mẹwaa iru rẹ ni ẹsan rẹ.