عن أنس بن مالك رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«مَنْ نَسِيَ صَلَاةً فَلْيُصَلِّ إِذَا ذَكَرَهَا، لَا كَفَّارَةَ لَهَا إِلَّا ذَلِكَ: {وَأَقِمِ الصَّلاةَ لِذِكْرِي} [طه: 14]».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 597]
المزيــد ...
Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Ẹni ti o ba gbagbe irun kan ki o yaa ki i nigba ti o ba ranti rẹ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fun un afi ìyẹn: (Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.) (Ta-Ha: 14)”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 597]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba gbagbe lati ki eyikeyii irun kan ti a ṣe e ni ọran-anyan titi asiko fi lọ, o jẹ dandan fun un lati tete ki o si yara lọ san an ni kete ti o ba ti ranti rẹ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ ati bibo fun ẹṣẹ gbigbe e ju silẹ afi ki Musulumi naa ki i nigba ti o ba ranti rẹ, Ọlọhun sọ ninu iwe Rẹ Alapọn-ọnle pé: (Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.) (Ta-Ha: 14), o n túmọ̀ si pe: Ki o si ki irun ti a gbagbe nigba ti o ba ti ranti rẹ.