عن بريدة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«إِنَّ الْعَهْدَ الَّذِي بَيْنَنَا وَبَيْنَهُمُ الصَّلَاةُ، فَمَنْ تَرَكَهَا فَقَدْ كَفَرَ».
[صحيح] - [رواه الترمذي والنسائي وابن ماجه وأحمد] - [سنن النسائي: 463]
المزيــد ...
Lati ọdọ Buraida- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Dajudaju adehun ti o wa laaarin wa ati laaarin wọn ni irun, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ”.
[O ni alaafia] - [Tirmiziy ati Nasaa'iy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti An-Nasaaiy - 463]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju adehun ati majẹmu ti o wa laaarin awọn Musulumi ati laaarin awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn alaigbagbọ ati awọn ṣọbẹ-selu ni irun kiki, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ.