+ -

عن عمران بن حصين رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«‌لَيْسَ ‌مِنَّا ‌مَنْ ‌تَطَيَّرَ أَوْ تُطُيِّرَ لَهُ، أَوْ تَكَهَّنَ أَوْ تُكُهِّنَ لَهُ، أَوْ سَحَرَ أَوْ سُحِرَ لَهُ، وَمَنْ عَقَدَ عُقْدَةً، وَمَنْ أَتَى كَاهِنًا فَصَدَّقَهُ بِمَا يَقُولُ فَقَدْ كَفَرَ بِمَا أُنْزِلَ عَلَى مُحَمَّدٍ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ».

[حسن] - [رواه البزار] - [مسند البزار: 3578]
المزيــد ...

Lati ọdọ Imraan ọmọ Husayn- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Kii ṣe ara wa ẹni ti o ba retí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú láti ara nǹkan tabi ti wọn ba a ṣe e, tabi ẹni ti o ba pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ tabi ti wọn sọ imọ kọ̀kọ̀ fun, tabi ẹni ti o ba sà sí èèyàn tabi ti wọn ba a sà sí èèyàn, ati ẹni tí ó bá ta kókó kan, ẹni tí ó bá wa ba ẹni tí n pe apemọra imọ kọ̀kọ̀, ti o wa gba ohun ti o sọ gbọ́, onítọ̀hún ti ṣe aigbagbọ si nǹkan ti wọn sọ̀kalẹ̀ fun Muhammad, ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a”.

[O daa] - [Al-Bazzaar ni o gba a wa] - [Musnad ti Al-Bazzaar - 3578]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe adehun iya fun ẹni ti o ba ṣe àwọn nǹkan kan ninu ijọ rẹ pẹlu gbólóhùn rẹ pe: “Kii ṣe ara wa”, ninu rẹ naa ni:
Akọkọ: “Ẹni ti o ba retí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú láti ara nǹkan tabi ti wọn ba a ṣe e”, ipilẹ rẹ ni: Titu ẹyẹ sílẹ̀ nígbà tí èèyàn ba fẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ kan bii ìrìn-àjò, tabi òwò, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti o ba fò lọ si apá ọ̀tún, o maa retí ìṣẹ̀lẹ̀ rere, o si maa ṣe nǹkan ti o gbèrò láti ṣe, ti o ba wa fò lọ sí apá òsì, o maa retí aburú, ko si nii ṣe nnkan ti o gbero lati ṣe mọ, ko ni ẹtọ ki èèyàn ṣe èyí fúnra rẹ, tabi ki o ni ki ẹlòmíràn ba oun ṣe e, ìrètí ìṣẹ̀lẹ̀ aburu latara èyíkéyìí nǹkan maa ko sínú ìyẹn, yálà nǹkan ti a n gbọ́ ni tabi nǹkan ti a n rí, bii ẹyẹ, tabi awọn ẹranko, tabi awọn alaabọ ara, tabi nọmba, tabi awọn ọjọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ẹẹkeji: “Ẹni ti o ba pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ tabi ti wọn sọ imọ kọ̀kọ̀ fun”, ẹni tí ó bá pe apemọra imọ kọkọ pẹlu lílo ìràwọ̀ ati nǹkan mìíràn, tabi ti o wa si ọdọ ẹni ti n pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ bii adágbigba ati ẹni ti o jọ ọ, ti o wa gba ohun ti o n sọ gbọ́ pẹ̀lú pipe apemọra imọ kọ̀kọ̀, o ti ṣe aigbagbọ si nǹkan ti wọn sọ̀kalẹ̀ fun Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a).
Ẹẹkẹta: “Ẹni ti o ba sà sí èèyàn tabi ti wọn ba a sà sí èèyàn”, oun naa ni ẹni tí o ṣe oogun funra rẹ, tabi o ni ki ẹlòmíràn ba oun ṣe e; lati fi ṣe ẹnikan ni anfaani, tabi ko inira bá a, tabi ti o ta kókó kan pẹlu dídi òwú ati oogun le e lori pẹlu kika àwọn gbólóhùn iṣọra ti o jẹ eewọ le e lori, ki o tun wa fẹnu fátẹ́gùn túẹ́túẹ́ sínú rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Dandan ni igbarale Ọlọhun, ati ìgbàgbọ́ ninu kadara Rẹ, ati ṣíṣe ìrètí aburú latara nǹkan, ati oogun, ati apemọra ìní-ìmọ̀ kọ̀kọ̀ tabi bíbéèrè lọ́wọ́ àwọn ti wọn n ṣe e - ni eewọ.
  2. Apemọra imọ kọ̀kọ̀ wa ninu ẹbọ ti o tako ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan.
  3. Ṣíṣe gbigba àwọn adagbigba ni olódodo ni eewọ ati lílọ ba wọn, a maa lẹ̀ papọ̀ mọ́ ìyẹn àwọn nǹkan mìíràn bii kíkà nǹkan ti a n pe ni atẹlẹwọ, ati ife ìmumi, ati awọn ìràwọ̀, ati wíwò wọ́n, kódà ki o kan jẹ́ láti mọ̀ nipa wọn lásán ni.