عَنْ مَحْمُودِ بْنِ لَبِيدٍ رضي الله عنه:
أَنَّ عُثْمَانَ بْنَ عَفَّانَ أَرَادَ بِنَاءَ الْمَسْجِدِ فَكَرِهَ النَّاسُ ذَلِكَ، وَأَحَبُّوا أَنْ يَدَعَهُ عَلَى هَيْئَتِهِ، فَقَالَ: سَمِعْتُ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ: «مَنْ بَنَى مَسْجِدًا لِلهِ بَنَى اللهُ لَهُ فِي الْجَنَّةِ مِثْلَهُ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 533]
المزيــد ...
Lati ọdọ Mahmud ọmọ Labid- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Dajudaju Uthman ọmọ ‘Affan fẹ kọ mọsalasi ni awọn eniyan ba korira ìyẹn, wọn nífẹ̀ẹ́ si ki wọn fi i kalẹ bi o ṣe wa, o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan fun Ọlọhun, Ọlọhun maa kọ iru rẹ fun un ninu alujanna”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 533]
Uthman ọmọ ‘Affan- ki Ọlọhun yọnu si i- fẹ tun mọsalasi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ni irisi ti o daa ju kikọ akọkọ rẹ lọ, ni awọn eniyan ba korira ìyẹn; fun nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu yiyi kikọ mọsalasi naa pada kuro nibi isẹsi kikọ rẹ ni aye Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- mọsalasi jẹ nnkan ti wọn mọ pẹlu amọ̀, ati pe òrùlé rẹ wọn mọ ọn latara imọ̀ ọ̀pẹ, ṣugbọn Uthman fẹ kọ ọ pẹlu awọn okuta ati ẹfun, Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ fun wọn nipa rẹ, ati pe oun gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan lati fi wa iyọnu Rẹ- Ọba ti ọla Rẹ ga- ti ko kii ṣe ni ti karimi tabi kagbọmi, Ọlọhun A san-an lẹsan ni eyi ti o daa julọ ninu ẹsan ninu iran iṣẹ rẹ, ati pe ẹsan yii oun ni ki Ọlọhun kọ iru rẹ fun un ninu alujanna.