عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللهُ عَنْهُ: أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«صَلَاةٌ فِي مَسْجِدِي هَذَا خَيْرٌ مِنْ أَلْفِ صَلَاةٍ فِيمَا سِوَاهُ إِلَّا الْمَسْجِدَ الْحَرَامَ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 1190]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
“Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun lọ ti a ki ni ibi ti o yatọ si i afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 1190]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé ọla ti o n bẹ fun irun ti a ki ni mọsalasi rẹ, pe o lọla ni ẹsan ju ẹgbẹrun irun ti a ki lọ ni ibi ti o yatọ si i ninu awọn mọsalasi aye, afi irun ti a ba ki ni mọsalasi ọwọ ni Makkah, oun lọla ju irun ti a ki ni mọsalasi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lọ.