+ -

«سَوُّوا صُفُوفَكُمْ، فَإِنَّ تَسْوِيَةَ الصَّفِّ مِنْ تَمَامِ الصَّلَاةِ».
[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Anas ọmọ Mālik - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Ẹ jẹ ki saafu yin o dọgba, nitori pe didọgba saafu ninu pipe irun lo wa»

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n pa awọn olukirun láṣẹ lati maa to saafu wọn daadaa, ki apakan wọn si ma yọ siwaju ju apakeji lọ, ki wọn si ma sun sẹyin, ati pe didọgba saafu ninu pipe irun lo wa, ati pe wiwọ saafu si jẹ aayẹ ati adinku ninu rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Ti èdè Sawahili Thai Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ti èdè Kyrgyz Ti èdè Dari
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe lofin níní akolekan gbogbo nkan ti o le mu irun pe ti yio si gbe e jina si adinku.
  2. Ọgbọn Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nibi ikọnilẹkọọ, latari bi o ṣe so idajọ papọ mọ okunfa rẹ; ki ọgbọn ṣiṣe ofin le fojú hàn, ati ki awọn ẹmi naa le ji giri lati ṣe amulo ofin.