1. Ojú ìwé wẹẹbu àkọ́kọ́
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi dajudaju ẹjẹ iṣan niyẹn, ṣugbọn maa fi irun silẹ ni odiwọn awọn ọjọ ti o fi maa n ri ẹjẹ nkan oṣu, lẹyin naa ki o wa wẹ ki o si kirun

عَنْ عَائِشَةَ أُمِّ المؤمنين رضي الله عنها أَنَّ فَاطِمَةَ بِنْتَ أَبِي حُبَيْشٍ سَأَلَتِ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَتْ:
إِنِّي أُسْتَحَاضُ فَلاَ أَطْهُرُ، أَفَأَدَعُ الصَّلاَةَ؟ فَقَالَ: «لَا، إِنَّ ذَلِكِ عِرْقٌ، وَلَكِنْ دَعِي الصَّلاَةَ قَدْرَ الأَيَّامِ الَّتِي كُنْتِ تَحِيضِينَ فِيهَا، ثُمَّ اغْتَسِلِي وَصَلِّي».

Lati ọdọ Aaisha iya àwọn Mumuni - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Faatimah ọmọ Abu Hubaysh bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere o wa sọ pe:
Dajudaju mo jẹ ẹni ti maa n ri ẹjẹ awaada ti mii si ki n si ni imọra, njẹ mo le fi irun silẹ? Ni o wa sọ pe: «Rara, dajudaju ẹjẹ iṣan niyẹn, ṣugbọn maa fi irun silẹ ni odiwọn awọn ọjọ ti o fi maa n ri ẹjẹ nkan oṣu, lẹyin naa ki o wa wẹ ki o si kirun».

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 325

Àlàyé

Faatimah ọmọ Hubaysh beere lọwọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni o wa sọ pe: Dajudaju ẹjẹ o ki n da lara mi ati pe o si maa n wa titi di igba ti kii ṣe igba ẹjẹ nkan oṣu, njẹ idajọ iyẹn le jẹ idajọ ẹjẹ nkan oṣu bii ti maa wa maa gbe irun ju silẹ? Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun un pe: Dajudaju ẹjẹ awaada ni, oun si ni ẹjẹ aisan kan ti o maa n ṣẹlẹ lati ipasẹ jija iṣan kan nibi apo ibimọ, ati pe kii ṣe ẹjẹ nkan oṣu, Ti asiko ẹjẹ nkan oṣu ba de, eyi ti o maa n ri ẹjẹ nkan oṣu níbẹ̀ lori ìṣesí oṣooṣu rẹ siwaju ki o to lugbadi aisan ẹjẹ awaada, ki o yaa fi irun ati aawẹ ati nkan ti o yatọ si mejeeji silẹ ni awọn nkan ti wọn kọ fun ẹni ti n ri ẹjẹ nkan oṣu kuro nibẹ ni asiko ẹjẹ nkan oṣu. Ti odiwọn igba yẹn ba ti wa tan, nigba naa wa jẹ ẹni ti o ti mọra kuro nibi ẹjẹ nkan oṣu, ki o yaa fọ aaye ẹjẹ yẹn, lẹyin naa ki o wẹ ara rẹ ni iwẹ ti o pe lati gbe ẹgbin kuro, lẹyin naa ki o wa ki irun.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Jijẹ dandan iwẹ fun obinrin nigba ti awọn ọjọ nkan oṣu rẹ ba pari.
  2. Jijẹ dandan irun fun ẹni ti n ri ẹjẹ awaada.
  3. Al-haydu ni: Ẹjẹ adamọ ti apo ibimọ maa n ti i jade lati ibi abẹ obinrin ti o ti di ẹni ọkunrin, eleyii ti yio maa ṣẹlẹ si i ni awọn ọjọ ti a ti mọ.
  4. Al-Istihaadoh ni: Sisan ẹjẹ ni igba ti kii ṣe asiko rẹ lati ẹnu apo ibimọ lai de ọgun rẹ.
  5. Iyatọ ti o wa laarin ẹjẹ nkan oṣu ati ẹjẹ awaada ni pe: Dajudaju ẹjẹ nkan oṣu dudu ti o ki ti oorun rẹ o si tun daa, amọ ẹjẹ awaada pupa ti o ṣàn ni ti ko si si oorun ti ko daa fun un.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

58 Èdè
EN English الإنجليزية
UR اردو الأوردية
ES Español الإسبانية
ID Indonesia الإندونيسية
UG ئۇيغۇرچە الأيغورية
BN বাংলা البنغالية
TR Türkçe التركية
RU Русский الروسية
BS Bosanski البوسنية
SI සිංහල السنهالية
HI हिन्दी الهندية
ZH 中文 الصينية
FA فارسی الفارسية
VI Tiếng Việt الفيتنامية
TL Tagalog تجالوج
KU Kurdî الكردية
HA Hausa الهوسا
PT Português البرتغالية
ML മലയാളം المليالم
TE తెలుగు التلغو
SW Kiswahili السواحيلية
TA தமிழ் التاميلية
MY မြန်မာ البورمية
TH ไทย التايلندية
DE Deutsch الألمانية
PS پښتو بشتو
AS অসমীয়া الأسامية
SQ Shqip الألبانية
SV Svenska السويدية
AM አማርኛ الأمهرية
NL Nederlands الهولندية
GU ગુજરાતી الغوجاراتية
KY Кыргызча القيرقيزية
NE नेपाली النيبالية
LT Lietuvių الليتوانية
PRS دری الدرية
SR Српски الصربية
SO Soomaali الصومالية
TG тоҷикӣ الطاجيكية
RW Kinyarwanda الكينياروندا
RO Română الرومانية
HU Magyar المجرية
CS Čeština التشيكية
MOS Moore الموري
MG Malagasy المالاجاشية
OM Oromoo الأورومو
KN ಕನ್ನಡ الكانادا
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan الأذربيجانية
UZ O‘zbek الأوزبكية
UK Українська الأوكرانية
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية