+ -

عن أُمِّ عَطِيَّةَ رَضي الله عنها، وكَانَتْ بايَعَت النبيَّ صلى الله عليه وسلم، قالت:
كُنَّا لا نَعُدّ الكُدرَةَ والصُّفْرَةَ بعدَ الطُّهرِ شيئًا.

[صحيح] - [رواه أبو داود بهذا اللفظ، ورواه البخاري بدون زيادة (بعد الطهر)] - [سنن أبي داود: 307]
المزيــد ...

Lati ọdọ Umu ‘Atiyyah - ki Ọlọhun yọnu si i - o jẹ ẹni ti o gbe adehun (ibura) fun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o sọ pe:
A jẹ ẹni ti kii ka omi ti awọ rẹ f'ara pẹ dúdú, ati omi alawọ iyeye lẹ́yìn imọra si nǹkan kan.

[O ni alaafia] - [Abu Daud ni o gba a wa pẹlu gbolohun yii, Bukhaariy naa si gba a wa lai ṣe afikun (lẹ́yìn imọra)] - [Sunanu ti Abu Daud - 307]

Àlàyé

Saabe lobinrin Umu ‘Atiyyah - ki Ọlọhun yọnu si i - sọ pe dajudaju awọn obinrin ni igba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o ki n ka omi ti o maa n jade ni oju ara obinrin- ti awọ rẹ f'ara pẹ dúdú, tabi awọ iyeye - lẹyin riri imọra nibi ẹjẹ nǹkan oṣu: wọn o ki n ka a si ẹjẹ nǹkan oṣu, nitori naa wọn o ki n fi irun ati aawẹ silẹ nitori rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Omi ti maa n sọkalẹ ni abẹ obinrin - lẹyin imọra nibi ẹjẹ oṣu - wọn o nii ka a si koda ki omi ti o fẹ dudu ati omi alawọ iyeye ti o wa latara ẹjẹ o wa nibẹ.
  2. Sisọkalẹ omi ti awọ rẹ sunmọ dudu ati omi alawọ iyeye ti o wa ni asiko riri ẹjẹ oṣu ati alaada, wọn o maa ka a si ẹjẹ oṣu; nítorí pé ẹjẹ kan ni ti o wa ni asiko rẹ, yatọ si pe o dà papọ mọ omi ni.
  3. Obìnrin o nii maa fi irun ati aawẹ silẹ nitori omi ti awọ rẹ sunmọ dudu ati omi alawọ iyeye ti o wa lẹ́yìn imọra, amọ yio maa ṣe aluwala, yoo si máa kirun.