عَنْ عَائِشَةَ أُمِّ المُؤْمِنينَ رَضي الله عنها أَنَّهَا قَالَتْ:
إِنَّ أُمَّ حَبِيبَةَ بِنْتَ جَحْشٍ الَّتِي كَانَتْ تَحْتَ عَبْدِ الرَّحْمَنِ بْنِ عَوْفٍ شَكَتْ إِلَى رَسُولِ اللهِ صلى الله عليه وسلم الدَّمَ، فَقَالَ لَهَا: «امْكُثِي قَدْرَ مَا كَانَتْ تَحْبِسُكِ حَيْضَتُكِ، ثُمَّ اغْتَسِلِي». فَكَانَتْ تَغْتَسِلُ عِنْدَ كُلِّ صَلَاةٍ.

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 334]
المزيــد ...

Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju o sọ pe:
Dajudaju Ummu Habeebah ọmọ Jahsh ti o wa labẹ 'Abdur Rahman ọmọ 'Aof, o gbe ẹjọ́ ẹjẹ lọ sọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ fun un pé: "Ẹ koraro ni odiwon igba ti nnkan oṣu rẹ ba fi de ọ mọle, lẹyin naa ki o wẹ". O si jẹ ẹni ti maa n wẹ nibi gbogbo irun.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 334]

Àlàyé

Ẹnikan ninu awọn saabe lobinrin fi ẹjọ àìdá ẹjẹ rẹ sun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa pa a láṣẹ kí ó má kirun ni odiwọn igba ti ẹjẹ nnkan oṣu rẹ fi maa n dè é mọle ṣíwájú ki àlámọ̀rí pajawiri yii o to ṣẹlẹ̀ si i, lẹyin naa o maa wẹ, o si maa kirun, o si jẹ ẹni ti maa n fínnú-fíndọ̀ wẹ fun gbogbo irun kọọkan.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Istihaadoh (Ẹjẹ awaada) ni: Ki jijade ẹjẹ maa tẹsiwaju lẹyin awọn ọjọ nnkan oṣu rẹ ti a ba saaba.
  2. Ẹni ti ẹjẹ awaada ń da lara rẹ yio ka ara rẹ si ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ni odiwọn awọn ọjọ ti nnkan oṣu fi maa n wa ba a nibẹ, ṣíwájú ki nnkan ti o ṣẹlẹ̀ si i to ṣẹlẹ̀ si i ninu ẹjẹ awaada.
  3. Ti odiwọn awọn ọjọ nnkan oṣu rẹ ipilẹ ba ti lọ, wọn maa ka a si ẹni ti o mọra kuro nibi nnkan oṣu- koda ki ẹjẹ awaada wà pẹlu rẹ- yio wẹ kuro ninu nnkan oṣù.
  4. Ẹni ti ẹjẹ awaada maa n da lara rẹ, ko jẹ dandan fun un lati maa wẹ fun gbogbo irun kọọkan; nitori pe iwẹ rẹ- ki Ọlọhun yọnu si i- igbiyanju imọ agbọye ẹsin lati ọdọ rẹ ni, ti o ba jẹ dandan ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- koba ṣe alaye fun un.
  5. Ẹni ti ẹjẹ awaada maa n da lara rẹ, ṣíṣe aluwala fun gbogbo irun kọọkan jẹ dandan fun un; nitori pe ẹgbin rẹ jẹ nnkan ti o n lọ tí kò dá, iru rẹ ni gbogbo ẹni ti ẹgbin rẹ ba n lọ gẹgẹ bi ẹni ti o ni itọ tí kò dá, tabi iso ti o n jade léraléra.
  6. Bibeere nnkan ti o ruju ninu awọn àlámọ̀rí ẹsin lọdọ awọn onimimọ, nigba ti obinrin yii fi ẹjọ sun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ti o si bi i leere nipa apọju ẹjẹ ti o n ṣẹlẹ̀ si i.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (55)