+ -

عَنْ عَمْرِو بْنُ سُلَيْمٍ الأَنْصَارِيُّ قَالَ: أَشْهَدُ عَلَى أَبِي سَعِيدٍ قَالَ: أَشْهَدُ عَلَى رَسُولِ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«الغُسْلُ يَوْمَ الجُمُعَةِ وَاجِبٌ عَلَى كُلِّ مُحْتَلِمٍ، وَأَنْ يَسْتَنَّ، وَأَنْ يَمَسَّ طِيبًا إِنْ وَجَدَ».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Amru ọmọ Sulaym Al-Ansari, o sọ pe: Mo n jẹ́rìí sí Abu Saheed pe o sọ pe: Mo n jẹrii si ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - o sọ pe:
«Iwẹ ọjọ Jimoh jẹ dandan lori gbogbo ẹni ti o ti balaga, ki o si fi pako run awọn eyin rẹ, ki o si lo lọ́fíńdà ti o ba ri».

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju iwẹ ọjọ Jimoh kanpa o da gẹgẹ bii ọranyan fun gbogbo ọkunrin ti o ti balaga ninu awọn musulumi ninu awọn ti Jimoh jẹ dandan fun. Ati pe ki o mọ awọn eyin rẹ pẹlu pákò ati nkan ti o jọ ọ. Ati ki o lo lọ́fíńdà pẹlu èyíkéyìí oorun aladidun.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Ti èdè Sawahili Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Titi èdè Gujarat Ti èdè Dari Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Kikanpa jíjẹ́ sunnah iwẹ ọjọ Jimoh lori gbogbo ọkunrin ti o jẹ musulumi ti o ti balaga.
  2. Ṣiṣe imọtoto ati mimu oorun ti a korira kuro nkan ti wọn fẹ ni ninu ofin ẹsin fun musulumi.
  3. Gbigbe ọjọ Jimoh tobi, ati igbaradi fun un.
  4. Kikan jijẹ sunnah rirun pako fun Jimọh nípá.
  5. Ṣiṣe lilo lọ́fíńdà ni sunnah pẹlu èyíkéyìí oorun aladidun-un ṣáájú lilọ fun Jimoh.
  6. Ti obinrin ba jade ni ile rẹ fun irun tabi nkan miran, ko lẹtọọ fun un ki o lo lọ́fíńdà; fun itọka sunnah lori ṣíṣe ìyẹn ni eewọ.
  7. Al-muhtalimu ni ẹni ti o ti balaga, ati pe bibalaga maa n ṣẹlẹ pẹlu awọn ami kan, mẹta ninu rẹ ko ọkunrin ati obinrin sinu oun ni: Alakọkọọ: Pipe ọmọ ọdun mẹẹdogun, ẹẹkeji: Ti irun ti o yi ba ti jade ni agbegbe oju ara, ẹẹkẹta: Dida atọ pẹlu ala tabi riri adun koda ki o ma si ala, ami kẹrin wa niyii obinrin nikan ni o ni in, oun ni: Ẹjẹ nǹkan oṣu, nigba ti obinrin ba ti ri ẹjẹ nǹkan oṣu o ti balaga.