+ -

عن أنس بن مالك رضي الله عنه:
أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ وَمُعَاذٌ رَدِيفُهُ عَلَى الرَّحْلِ قَالَ: «يَا مُعَاذُ بْنَ جَبَلٍ»، قَالَ: لَبَّيْكَ يَا رَسُولَ اللهِ وَسَعْدَيْكَ، قَالَ: «يَا مُعَاذُ»، قَالَ: لَبَّيْكَ يَا رَسُولَ اللهِ وَسَعْدَيْكَ، ثَلَاثًا، قَالَ: «مَا مِنْ أَحَدٍ يَشْهَدُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَأَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللهِ صِدْقًا مِنْ قَلْبِهِ إِلَّا حَرَّمَهُ اللهُ عَلَى النَّارِ»، قَالَ: يَا رَسُولَ اللهِ، أَفَلَا أُخْبِرُ بِهِ النَّاسَ فَيَسْتَبْشِرُوا؟ قَالَ: «إِذًا يَتَّكِلُوا». وَأَخْبَرَ بِهَا مُعَاذٌ عِنْدَ مَوْتِهِ تَأَثُّمًا.

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- pe:
Mu’aadh wa lẹ́yìn Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori nnkan ọgun, o sọ pe: "c2">“Irẹ Mu’aadh ọmọ Jabal”, o sọ pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo si n wa oriire fun dida ẹ lóhùn, o tun sọ pe: "c2">“Irẹ Mu’aadh”
, o sọ pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo si n wa oriire fun dida ẹ lóhùn, lẹẹmẹta, o sọ pe: "c2">“Ko si ẹni kankan ti o n jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si lododo afi Allahu, ati pe Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni lododo lati inu ọkan rẹ, afi ki Ọlọhun ṣe ina leewọ fun un”, o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, njẹ mi ko nii maa sọ ọ fun awọn eniyan ki wọn le dunnu? O sọ pe: "c2">“Ti o ba ri bẹẹ wọn maa gbara le e”. Ni Mu’aadh wá sọ ọ́ nigba ti o fẹ ku ki o ma baa kó sínú ẹṣẹ.
O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Mu’aadh ọmọ Jabal- ki Ọlọhun yọnu si i- wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori nǹkan ọ̀gùn rẹ, o wa pe e: Irẹ Mu’aadh? O paara pipe e rẹ lẹẹmẹta; lati fi pataki nnkan ti o fẹ sọ rinlẹ.
Ati pe gbogbo ìyẹn ni Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i- n da a lohun pẹlu ọrọ rẹ pé: "c2">“LABBAEKA YAA ROSUULALLOOHI WA SAHDAEK”
, o n túmọ̀ sí pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun ni idahun kan lẹyin idahun, mo si n tọrọ oriire fun jijẹ ìpè rẹ.
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pe ko si ẹnikẹni ti o n jẹrii pe LAA ILAAHA ILLALLOOH, itumọ rẹ ni pe: Ko si ẹni ti a le jọsin fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ afi Ọlọhun, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, lododo lati inu ọkan rẹ lai parọ, ti o ba ku lori iṣesi yii, Ọlọhun maa ṣe ina leewọ fun un.
Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i- wa beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe ṣe ki oun sọ ọ fun awọn eniyan ki wọn le yọ ki wọn si dunnú si dáadáa?
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa paya pe ki wọn ma baa gbara le e, ti iṣẹ wọn fi maa kere.
Mu’aadh ko sọ hadiisi naa fun ẹnikẹni afi ṣiwaju iku rẹ; ni ti ipaya kikosi inu ẹṣẹ fifi imọ pamọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Irẹlẹ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi fifi Mu’aadh sẹyin rẹ lori nnkan ọ̀gùn rẹ.
  2. Ọ̀nà ikọnilẹkọọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, nigba ti o paara ipe rẹ fun Mu’aadh lati lè jẹ ki o maa fi ọkàn ba nnkan ti o fẹ sọ lọ.
  3. Ninu majẹmu jijẹrii pe: Ko si ẹni ti ijọsin tọ si afi Allahu ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni ni ki ẹni ti o sọ ọ jẹ olododo ti o ni amọdaju ti ko jẹ onirọ tabi oniyemeji.
  4. Àwọn ti wọn mu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo ko nii ṣe gbere ninu ina jahannamọ, ti wọn bá wọ̀ ọ́ torí awọn ẹṣẹ wọn; wọn maa mu wọn jade lẹyin ti wọn ba mọ.
  5. Ọla ti o n bẹ fun ijẹrii mejeeji fun ẹni ti o ba sọ ọ lododo.
  6. Jijẹ ẹtọ gbigbe sísọ hadiisi ju silẹ ni awọn iṣesi kan ti ibajẹ ba lè ti ara rẹ jẹ yọ.