+ -

عَنْ عَبْدِ اللَّهِ بْنِ عَمْرٍو رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمَا عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«المُسْلِمُ مَنْ سَلِمَ المُسْلِمُونَ مِنْ لِسَانِهِ وَيَدِهِ، وَالمُهَاجِرُ مَنْ هَجَرَ مَا نَهَى اللَّهُ عَنْهُ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 10]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
«Musulumi ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ ati ọwọ rẹ, ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o yan nkan ti Ọlọhun kọ lodi».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 10]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe dajudaju musulumi ti Isilaamu rẹ pe oun ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ, ko nii bu wọn, ko si nii ṣepe fun wọn, ko si nii sọ ọrọ wọn lẹyin, ko si nii maa fi ahọn rẹ tan èyíkéyìí ninu awọn iran ṣuta ka laarin wọn, Ti wọn si tun la ni ọwọ rẹ, ko si nii tayọ ẹnu-ala si wọn, ko si nii gba awọn dukia wọn ni ọna aitọ, ati nkan ti o jọ ìyẹn, Ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o gbe nkan ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe leewọ jusilẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Isilaamu o le pe ayaafi pẹlu àìfi ṣuta kan ẹlòmíràn, o jẹ èyí tí a fi oju ri ni abi èyí tí a o le ni ìmọ̀lára rẹ.
  2. Wọn ṣa ahọn ati ọwọ lẹsa pẹlu didarukọ wọn; latari pipọ awọn aṣiṣe wọn ati awọn inira wọn, ati pe dajudaju ọdọ wọn ni ọpọlọpọ aburu ti maa n wa.
  3. Ṣiṣenilojukokoro lori gbigbe awọn ẹṣẹ silẹ ati ṣíṣe nkan ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pa lasẹ.
  4. Ẹni ti o ni ọla julọ ninu awọn musulumi ni ẹni ti o pe awọn iwọ Ọlọhun ati awọn iwọ awọn musulumi.
  5. Itayọ aala le jẹ ọrọ tabi iṣe.
  6. Hijrah ti o pe oun ni yiyan nkan ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe ni eewọ lodi.