عَنْ المُغِيرَةِ رضي الله عنه قَالَ:
كُنْتُ مَعَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فِي سَفَرٍ، فَأَهْوَيْتُ لِأَنْزِعَ خُفَّيْهِ، فَقَالَ: «دَعْهُمَا، فَإِنِّي أَدْخَلْتُهُمَا طَاهِرَتَيْنِ» فَمَسَحَ عَلَيْهِمَا.
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 206]
المزيــد ...
Lati ọdọ Al-Mughiirah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe.
Mo wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni irin-ajo kan, ni mọ ba bẹrẹ lati bọ abọsẹsẹ alawọ rẹ mejeeji, ni o wa sọ pe: «Fi wọn silẹ, nitori pe dajudaju mo ti mejeeji bọ ọ ni mimọ ni» ni o wa fi ọwọ pa mejeeji.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 206]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ni ọkan ninu awọn irin-ajo rẹ, ni o wa ṣe aluwala, Nigba ti o wa débi fifọ ẹsẹ mejeeji, Al- Mughiirah ọmọ Shu‘bah - ki Ọlọhun yọnu si i - na ọwọ rẹ mejeeji lati bọ nkan ti o wa ni ẹsẹ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni abọsẹsẹ alawọ lati fọ ẹsẹ rẹ mejeeji. Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: Fi mejeji silẹ ma bọ wọn, torí pé dajudaju mo ti ẹsẹ mi mejeeji bọ inu abọsẹsẹ alawọ mejeeji ti mo si wa lori imọra, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa fi ọwọ pa abọsẹsẹ alawọ rẹ mejeeji lati fi jirọ fifọ ẹsẹ mejeeji.