عَنْ عَائِشَةَ أُمِّ المؤمنين رضي الله عنها:
أَنَّ أُمَّ سَلَمَةَ ذَكَرَتْ لِرَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كَنِيسَةً رَأَتْهَا بِأَرْضِ الْحَبَشَةِ، يُقَالُ لَهَا مَارِيَةُ، فَذَكَرَتْ لَهُ مَا رَأَتْ فِيهَا مِنَ الصُّوَرِ، فَقَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «أُولَئِكَ قَوْمٌ إِذَا مَاتَ فِيهِمُ الْعَبْدُ الصَّالِحُ، أَوِ الرَّجُلُ الصَّالِحُ، بَنَوْا عَلَى قَبْرِهِ مَسْجِدًا، وَصَوَّرُوا فِيهِ تِلْكَ الصُّوَرَ، أُولَئِكَ شِرَارُ الْخَلْقِ عِنْدَ اللهِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 434]
المزيــد ...
Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Dajudaju Ummu Salamah dárúkọ ṣọọṣi kan ti o ri ni ilẹ̀ Habasha fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, wọn n pe e ni Maariyah, o wa sọ nnkan ti o ri nibẹ fun un ninu awọn aworan, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pe: "Awọn wọnyẹn ni ìjọ kan, ti ẹru rere ba ku ninu wọn tabi ọkùnrin rere, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ, wọn yoo si ya awọn aworan yẹn síbẹ̀, awọn wọnyẹn ni awọn ti wọn buru julọ ninu ẹda lọdọ Ọlọhun".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 434]
Iya awọn olugbagbọ Ummu Salamah- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe dajudaju nigba ti oun fi wa lori ilẹ Habasha, oun ri ṣọọṣi kan- wọn n pe e ni Maariyah- ti awọn aworan ati awọn ẹṣọ ati awọn fọto n bẹ nibẹ; ni ti ìyàlẹ́nu latara ìyẹn! Bayii ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ṣàlàyé awọn okunfa gbigbe awọn aworan yii síbẹ̀; O sọ pe: Dajudaju awọn ti o dárúkọ wọnyii ti ẹni rere ba ku laaarin wọn, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ ti wọn ma maa kirun nibẹ, ti wọn si maa ya awọn aworan yẹn, O ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe yẹn jẹ ẹni ti o buru julọ ninu ẹda lọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-; nitori pe iṣe rẹ maa ja si dida orogun pọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.