عن أبي مَرْثَدٍ الغَنَوِيّ رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«لَا تَجْلِسُوا عَلَى الْقُبُورِ، وَلَا تُصَلُّوا إِلَيْهَا».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 972]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Marthad Al-ganawiy – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe:
«Ẹ ma ṣe jokoo si ori awọn sàréè, ẹ ko si gbọdọ kirun si i lara».

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 972]

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kọ kuro nibi jijokoo si ori awọn sàréè.
Gẹgẹ bi o ṣe kọ kuro nibi kiki irun si awọn sàréè, bii ki sàréè o wa ni agbegbe idojukọ olukirun; nitori pe dajudaju ìyẹn wa ninu awọn atẹgun imu-orogun-mọ Ọlọhun.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Kikọ kuro nibi kiki irun ni itẹ tabi ni aarin rẹ tabi si i lára ayaafi irun oku gẹgẹ bi o ṣe fi ẹsẹ mulẹ ninu sunnah.
  2. Kikọ kuro nibi kiki irun si sàréè lati dena ijẹ-atẹgun imu-orogun-mọ Ọlọhun.
  3. Isilaamu kọ kuro nibi ikọja ààlà nibi awọn sàréè ati kuro nibi yiyẹpẹrẹ rẹ, ko gbọdọ si àṣejù ko si gbọdọ si aseeto.
  4. Ọwọ Musulumi si ṣẹku lẹyin iku rẹ, latari gbolohun rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ti o sọ pe: (Rirun eegun oku da gẹgẹ bii rirun un (eegun) ni ààyè ni).
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (62)