عَنْ أَبِي سَعِيدٍ الخُدْرِيَّ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ -وَكَانَ غَزَا مَعَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ ثِنْتَيْ عَشْرَةَ غَزْوَةً- قَالَ: سَمِعْتُ أَرْبَعًا مِنَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَأَعْجَبْنَنِي، قَالَ:
«لاَ تُسَافِرِ المَرْأَةُ مَسِيرَةَ يَوْمَيْنِ إِلَّا وَمَعَهَا زَوْجُهَا أَوْ ذُو مَحْرَمٍ، وَلاَ صَوْمَ فِي يَوْمَيْنِ: الفِطْرِ وَالأَضْحَى، وَلاَ صَلاَةَ بَعْدَ الصُّبْحِ حَتَّى تَطْلُعَ الشَّمْسُ، وَلاَ بَعْدَ العَصْرِ حَتَّى تَغْرُبَ، وَلاَ تُشَدُّ الرِّحَالُ إِلَّا إِلَى ثَلاَثَةِ مَسَاجِدَ: مَسْجِدِ الحَرَامِ، وَمَسْجِدِ الأَقْصَى، وَمَسْجِدِي هَذَا».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 1995]
المزيــد ...
Lati ọdọ Sa‘eed Al-Khuduriy - ki Ọlọhun yọnu si i - o jẹ ẹni ti o kopa ninu ogun mejila pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: Mo gbọ nkan mẹẹrin ni ẹnu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o si jọ mi l'oju, o sọ pe:
«Obinrin ko gbọdọ ṣe irin-ajo ti o to ọjọ meji ayaafi ki ọkọ rẹ tabi eleewọ rẹ o wa pẹlu rẹ, ko si si aawẹ ni ọjọ meji: Itunu awẹ ati ileya, ko si tun si irun lẹyin asunbaa titi ti oorun o fi yọ, ko si si lẹyin Asri naa titi ti yio fi wọ, wọn o si tun gbọdọ di ẹru irin-ajo ayaafi lati lọ si masalasi mẹta: Masalasi abeewọ, ati masalasi aqsa, ati masalasi mi yii».
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 1995]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ kuro nibi awọn alamọri mẹẹrin kan:
Alakọkọọ rẹ: Kikọ fun obinrin kuro nibi ṣiṣe irin-ajo ọjọ meji lai si pẹlu ọkọ rẹ tabi ẹnikan ninu awọn eleewọ rẹ oun naa ni ẹni ti wọn ṣe fifẹ ẹ (ọmọbinrin naa) ni eewọ fun un ni ṣiṣe leewọ gbere ninu awọn alasunmọ-ọn, gẹgẹ bii ọmọ ati baba, ọmọkùnrin ọmọ-iya rẹ ọkunrin ati ọmọkùnrin ọmọ-iya rẹ obinrin, ati ọmọ-iya baba rẹ l'ọkunrin ati ọmọ-iya iya rẹ l'ọkunrin, ati awọn to jọ bẹ́ẹ̀.
Ẹlẹẹkeji rẹ: Kikọ kuro nibi gbigba aawẹ ọjọ ọdun itunu ati ọjọ ọdun ileya, ki baa ṣe pe musulumi gba mejeeji ni gbigba ti ẹ̀jẹ́, tabi aṣegbọrẹ, tabi itanran.
Ẹlẹẹkẹta rẹ: Kikọ kuro nibi kiki irun naafila lẹyin irun Asri titi ti oorun o fi wọ, ati lẹyin yiyọ aarọ titi ti oorun o fi yọ.
Ẹẹkẹrin rẹ: Kikọ kuro nibi ṣiṣe irin-ajo lọ si aaye kan ninu awọn aaye ati nini adisọkan ọla rẹ ati nini adisọkan pe adipele ẹsan wa nibẹ yatọ si awọn masalasi mẹta, nitori naa a ko gbọdọ di ẹru irin-ajo lọ si ibi ti o yatọ si wọn lati lọ kirun nibẹ, torí pé dajudaju adipele o ni maa ba ẹsan ayaafi ni awọn masalasi mẹta yii, masalasi abeewọ (kahbah), ati masalasi Anabi, ati masalasi aqsa.