عَنْ أَبِي سَعِيدٍ الْخُدْرِيِّ رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«إِنَّ الدُّنْيَا حُلْوَةٌ خَضِرَةٌ، وَإِنَّ اللهَ مُسْتَخْلِفُكُمْ فِيهَا، فَيَنْظُرُ كَيْفَ تَعْمَلُونَ، فَاتَّقُوا الدُّنْيَا وَاتَّقُوا النِّسَاءَ، فَإِنَّ أَوَّلَ فِتْنَةِ بَنِي إِسْرَائِيلَ كَانَتْ فِي النِّسَاءِ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2742]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Dajudaju aye jẹ nnkan ti o dun ti o si tutu, ati pe dajudaju Ọlọhun n fi yin ṣe arole nibẹ, ti yoo maa wo nnkan ti ẹ ń ṣe, ẹ bẹru aye ki ẹ si bẹru obinrin, dajudaju akọkọ fitina awọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ lara obinrin".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2742]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju aye dun nibi itọwo, o si tutu nibi riri, ti ọmọniyan maa gba ẹtanjẹ pẹlu rẹ ti yoo si tẹ̀rì sinu rẹ ti yoo si sọ ọ di eyi ti o tobi julọ ninu ironu rẹ. Ati pe dajudaju Ọlọhun- mimọ ni fun Un- fi awọn kan ninu wa role fun awọn kan ni igbesi aye yìí, ki O le maa wo bi a ṣe maa ṣiṣẹ, njẹ a maa tẹle E, tabi a maa yapa Rẹ? Lẹyin naa, o sọ pe: Ẹ ṣọ́ra ki igbadun aye ati ọṣọ rẹ ma tan yin jẹ, ti o wa maa mu yin gbe nnkan ti Ọlọhun pa yin láṣẹ rẹ ju silẹ, ati kiko si nnkan ti O kọ kuro fun yin nibẹ. Ati pe ninu nnkan ti o jẹ dandan julọ lati ṣọ́ra kuro ninu rẹ ninu awọn wahala aye ni wahala obinrin, ati pe o jẹ akọkọ wahala ti awọn ọmọ Ísírẹ́lì ko síbẹ̀.