عَنْ عَائِشَةَ أُمِّ المُؤْمِنين رَضِيَ اللَّهُ عَنْهَا، قَالَتْ:
مَا رَأَيْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ مُسْتَجْمِعًا قَطُّ ضَاحِكًا، حَتَّى أَرَى مِنْهُ لَهَوَاتِهِ، إِنَّمَا كَانَ يَتَبَسَّمُ.
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6092]
المزيــد ...
Lati ọdọ iya awọn olugbagbọ ododo, A'isha ki Ọlọhun bawa yọnu sì i, o sọ bayi pe:
Mi o ri ki anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba - ki o fi gbogbo ara rẹrin titi ti maa fì wá rí bèlúbèlú rẹ̀, ṣugbọn Anọbi aa máa rẹrin musẹ.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6092]
Ki Ọlọhun bá wa yọnu si A'isha, Oun ló fún wa niro pe Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - Kii mọn fi gbogbo ara rẹrin ti a fi waa rí belubelu rẹ, (belubelu ni ẹran ti o so mọ oke ọ̀nà ọ̀fun) ṣugbọn Anọbi aa maa rẹrin musẹ.