عن أنس بن مالك رضي الله عنه قال:
كَانَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ أَحْسَنَ النَّاسِ خُلُقًا.
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 2310]
المزيــد ...
Lati ọdọ Anas ọmọ Mālik – ki Allāh yọnu si i – o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti o dara julọ ni iwa.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 2310]
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti o pe julọ ni iwa, o si tun gba iwájú nibi gbogbo iwa ati nkan daadaa, nibi ọrọ to daa, ati ṣiṣe daadaa, ati titu oju ka, ati mimu suta kuro ati nini atemọra rẹ lati ọdọ ẹlòmíràn.