عَنْ سَعْدٍ رضي الله عنها قَالَ:
جَاءَ أَعْرَابِيٌّ إِلَى رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَقَالَ: عَلِّمْنِي كَلَامًا أَقُولُهُ، قَالَ: «قُلْ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، اللهُ أَكْبَرُ كَبِيرًا، وَالْحَمْدُ لِلَّهِ كَثِيرًا، سُبْحَانَ اللهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ، لَا حَوْلَ وَلَا قُوَّةَ إِلَّا بِاللهِ الْعَزِيزِ الْحَكِيمِ» قَالَ: فَهَؤُلَاءِ لِرَبِّي، فَمَا لِي؟ قَالَ: «قُلْ: اللهُمَّ اغْفِرْ لِي وَارْحَمْنِي وَاهْدِنِي وَارْزُقْنِي».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2696]
المزيــد ...
Lati ọdọ Sa'd- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Larubawa oko kan wa ba ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Kọ mi ni ọrọ kan ti maa maa sọ ọ: O sọ pe: " Sọ pe: Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, Allahu Akbar kabeeran, wal amdulillah katheeran, Subhaanallah Robbil 'aalameen, laa haola wa laa quwwata illa billahil Azeezil Hakeem" o sọ pe: Awọn wọnyi jẹ ti Oluwa mi, ki ni o jẹ temi? O sọ pe: Sọ pe: Allahumo igfir liy warhamniy wahdiniy warzuqniy".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2696]
Arakunrin kan ninu awọn ti wọn n gbe oko beere lọwọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati kọ oun ni iranti kan ti o ma maa sọ ọ, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: Sọ pe: "Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu" o bẹ̀rẹ̀ pẹlu jijẹrii imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo, ìtumọ̀ rẹ ni pe ko si ẹni ti a le jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu, "Allahu Akbar kabeeran" O n túmọ̀ si pe: Ọlọhun tobi ju gbogbo nnkan lọ O si ga ju wọn lọ, "Wal amdulillah katheeran" O túmọ̀ si pe: Ọpẹ ni fun Ọlọhun ni eyi ti o pọ, lori awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ ati awọn idẹra Rẹ ti ko ṣee ka, "Subhaanallah Robbil 'aalameen" O túmọ̀ si pe: O mọ kuro nibi adikun, "Laa aola wa laa quwwata illa billahil Azeezil Hakeem" O túmọ̀ si pe: Ko si ìyípadà lati isẹsi kan si isẹsi miiran afi pẹlu Ọlọhun ati iranlọwọ Rẹ ati ifiniṣe-kongẹ Rẹ, Arakunrin naa sọ pe: Awọn ọrọ wọnyii jẹ ti Oluwa mi lati ṣe iranti Rẹ ati gbigbe E tobi, ki ni o wa fun mi ninu adura fun ara mi? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: Sọ pe: "Allahumo igfir liy", Ọlọhun mi, fori jin mi Pẹlu pipa awọn aburu rẹ ati bibo o, "Warhamniy" ki O si kẹ mi Pẹlu mimu awọn anfaani ti ọrun ati ti aye ba mi, "Wahdiniy" ki O si tọ mi sọ́nà Si eyi ti o dara julọ ninu awọn isẹsi ati si oju ọna taara, "Warzuqniy" ṣe arisiki fun mi Pẹlu owo halaali ati alaafia ati gbogbo oore ati alaafia.