عَن عبدِ اللهِ بن خُبَيب رضي الله عنه أنه قال:
خَرَجْنَا فِي لَيْلَةٍ مَطِيرَةٍ وَظُلْمَةٍ شَدِيدَةٍ، نَطْلُبُ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ؛ يُصَلِّي لَنَا، قَالَ: فَأَدْرَكْتُهُ، فَقَالَ: «قُلْ»، فَلَمْ أَقُلْ شَيْئًا، ثُمَّ قَالَ: «قُلْ»، فَلَمْ أَقُلْ شَيْئًا، قَالَ: «قُلْ»، فَقُلْتُ: مَا أَقُولُ؟ قَالَ: «{قُلْ هُوَ اللهُ أَحَدٌ} وَالْمُعَوِّذَتَيْنِ حِينَ تُمْسِي وَتُصْبِحُ ثَلَاثَ مَرَّاتٍ، تَكْفِيكَ مِنْ كُلِّ شَيْءٍ».
[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي والنسائي] - [سنن الترمذي: 3575]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Khubayb - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:
A jade ni alẹ ọjọ kan ti ojo n rọ ti o si ṣokunkun gidigidi, ti a n wa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a; lati kirun fun wa, o sọ pe: Ni a ba ri i, ni o wa sọ pe: «Sọ», mi o si sọ nkankan, lẹyin naa o sọ pe: «Sọ», mi ò si sọ nkankan, o sọ pe: «Sọ», ni mo ba sọ pe: Kini maa sọ? O sọ pe: «{Qul Uwal Laahu ahad} ati Al-mu‘awwidhatayn (Falaqi ati Naasi) nigba ti o ba di irọlẹ ati ti o ba di afẹmọjumọ ni igba mẹta, yio to ọ nibi gbogbo nkan».
[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 3575]
Saabe abiyi tii ṣe Abdullāh ọmọ Khubayb - ki Ọlọhun yọnu si i - n funni niroo pe: Awọn jade ni alẹ kan ti ojo pọ gan ti okunkun naa si dudu kirikiri, lati lọ wa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-; ki o le ki irun fun wọn, ti wọn si ri i, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: "Qul" iyẹn ni pe: ka, ko si ka nkankan, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa tun ọrọ rẹ wi fun un, ni Abdullāh wa sọ pe: Kini ki n ka irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun? Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: Ka suuratul Ikhlaas {Qul Uwal Laahu ahad}, ati Al-Mu‘awwidhatayn {Qul a‘uudhu bi robbil falaq}, ati {Qul a‘uudhu bi robbin naas}, ni asiko irọlẹ, ati asiko aarọ, ni ẹẹmẹta yio maa sọ ọ kuro nibi gbogbo aburu, ti yio si la ọ kuro nibi gbogbo ibajẹ.