عن عبد الله بن عمرو بن العاص رضي الله عنهما عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«الْكَبَائِرُ: الْإِشْرَاكُ بِاللهِ، وَعُقُوقُ الْوَالِدَيْنِ، وَقَتْلُ النَّفْسِ، وَالْيَمِينُ الْغَمُوسُ».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 6675]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Awọn ẹṣẹ nlanla ni: Mimu orogun pẹlu Ọlọhun, ṣiṣẹ baba ati ìyá, pipa ẹmi, ati bibura lori irọ”.
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6675]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe awọn nlanla ninu awọn ẹṣẹ, àwọn ni eyi ti wọn ṣe adehun iya fun ẹni ti o ba ṣe e pẹlu adehun iya ti o le koko ni aye tabi ni ọrun.
Akọkọ ninu ẹ ni “Mimu orogun pọ mọ Ọlọhun”: Oun ni yiyi eyikeyii iran ninu awọn iran ijọsin fun ẹni ti o yatọ si Ọlọhun, ati gbigbe ẹni ti o yatọ si Ọlọhun si ipo Ọlọhun nibi nnkan ti o jẹ awọn ẹsa Ọlọhun nibi ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin Rẹ, ati nibi jijẹ Oluwa Rẹ ati nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ.
Ikeji nibẹ ni “Ṣiṣẹ baba ati iya”: Oun ni gbogbo nnkan ti o le sọ fifi suta kan baba ati iya di dandan ni ti ọrọ ni tabi iṣe, ati gbigbe ṣiṣe daadaa si wọn ju silẹ.
Ikẹta nibẹ ni “pipa ẹmi”: Laini ẹtọ, gẹgẹ bii pipa ẹmi ni ti abosi ati ni ti itayọ ẹnu-àlà.
Ikẹrin nibẹ ni “Bibura lori irọ”: Oun ni bibura ni ẹni tí n pa irọ ti o si mọ̀ pé irọ́ ni oun n pa, wọn sọ ọ ni orúkọ yẹn; nitori pe o maa n tẹ ẹni ti o n pa a ri sinu ẹṣẹ tabi inu ina.