+ -

عَنْ جَابِرِ بْنِ عَبْدِ اللهِ رضي الله عنهما أَنَّهُ سَمِعَ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«إِذَا دَخَلَ الرَّجُلُ بَيْتَهُ، فَذَكَرَ اللهَ عِنْدَ دُخُولِهِ وَعِنْدَ طَعَامِهِ، قَالَ الشَّيْطَانُ: لَا مَبِيتَ لَكُمْ، وَلَا عَشَاءَ، وَإِذَا دَخَلَ، فَلَمْ يَذْكُرِ اللهَ عِنْدَ دُخُولِهِ، قَالَ الشَّيْطَانُ: أَدْرَكْتُمُ الْمَبِيتَ، وَإِذَا لَمْ يَذْكُرِ اللهَ عِنْدَ طَعَامِهِ، قَالَ: أَدْرَكْتُمُ الْمَبِيتَ وَالْعَشَاءَ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2018]
المزيــد ...

Lati ọdọ Jabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- pe o gbọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pé:
"Ti ọkùnrin ba wọ inu ile rẹ, ti o wa ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ ati nibi oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ko si ibusun fun yin ko si si oúnjẹ alẹ naa, ti o ba wa wọle, ti ko ṣe iranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ẹ ti ri ibùsùn, ti ko ba ti dárúkọ Ọlọhun nibi oúnjẹ rẹ, o maa sọ pe: Ẹ ti ri ibusun ati oúnjẹ alẹ".

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2018]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pàṣẹ pẹlu riranti Ọlọhun nigba wiwọ inu ile ati ṣíwájú jijẹ oúnjẹ, ti o ba ranti Ọlọhun pẹlu sisọ pe: (Bismillah) nigba ti o ba wọ inu ile rẹ ati ìbẹ̀rẹ̀ jijẹ oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ fun awọn oluranlọwọ rẹ pé: Ko si ipin fun yin lati sun tabi lati jẹun alẹ ninu ile yii ti ẹni ti o ni i ti wa iṣọra kuro lọdọ yin pẹlu riranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. Ṣugbọn ti ọkùnrin ba wọ ile rẹ ti ko ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ tabi nigba jijẹ oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ fun awọn oluranlọwọ rẹ pe wọn ti ri ibusun ati oúnjẹ alẹ ninu ile yii.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe iranti Ọlọhun nigba wiwọ inu ile ati oúnjẹ ni nnkan ti a fẹ, nitori pe Shaitan maa n gbe inu awọn ile, ti o si maa n jẹ oúnjẹ awọn ara ile ti wọn ko ba dárúkọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
  2. Shaitan maa n ṣọ ọmọ Adam nibi iṣẹ rẹ ati ìwà rẹ ati nibi awọn àlámọ̀rí rẹ pata, ti o ba gbagbe lati ranti Ọlọhun, ọwọ rẹ maa tẹ erongba rẹ lọdọ rẹ.
  3. Iranti maa n le Shaitan dànù.
  4. Gbogbo èṣù kọọkan lo ni awọn ọmọlẹyin rẹ ati awọn ààyò rẹ ti wọn maa n dunnu pẹlu ọrọ rẹ ti wọn si n tẹle àṣẹ rẹ.