عن عبد الله بن عمرو رضي الله عنهما أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«الدُّنْيَا مَتَاعٌ، وَخَيْرُ مَتَاعِ الدُّنْيَا الْمَرْأَةُ الصَّالِحَةُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 1467]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abdullah ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ayé ìgbádùn ni, eyi ti o loore ju ninu ìgbádùn ayé ni obìnrin rere”
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 1467]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ayé pẹ̀lú nǹkan ti n bẹ ninu ẹ jẹ nǹkan ti eeyan maa n gbádùn fun ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn naa ni o maa kúrò, ati pe ìgbádùn rẹ ti o ni ọlá jù ni obìnrin rere, eyi ti o ṣe pe ti o ba wo o yoo dun un ninu, ti o ba pa a láṣẹ yoo tẹle e, ti ko ba si ni tòsí o maa ṣọ́ ọ ninu ẹ̀mí ara rẹ ati dúkìá rẹ.