عن عائشة رضي الله عنها زوج النبي صلى الله عليه وسلم عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«إِنَّ الرِّفْقَ لَا يَكُونُ فِي شَيْءٍ إِلَّا زَانَهُ، وَلَا يُنْزَعُ مِنْ شَيْءٍ إِلَّا شَانَهُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2594]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- ìyàwó Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Dájúdájú ẹ̀lẹ̀ ko nii wa ninu nǹkan ayafi ki o ko ọ̀ṣọ́ ba a, wọn ko si nii yọ ọ kuro ninu nǹkan ayafi ki o ko àléébù ba a”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2594]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹ̀lẹ̀ ninu ọrọ ati ìṣe maa n lé àlámọ̀rí kún ni ẹwà ati pipe ati dídára, ohun ti o yẹ julọ ni ki ẹni ti ba n fi ẹ̀lẹ̀ ṣe nnkan o ri bukaata rẹ gbọ́.
Àìsí ẹ̀lẹ̀ maa n ko àléébù ba àlámọ̀rí ni, ko si nii jẹ ki èèyàn o ri bukaata rẹ gbọ, ti o ba wa ri bukaata naa gbọ, o maa jẹ pẹlu inira ni.