عن أنس بن مالك رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«إِنَّ اللهَ لَيَرْضَى عَنِ الْعَبْدِ أَنْ يَأْكُلَ الْأَكْلَةَ فَيَحْمَدَهُ عَلَيْهَا، أَوْ يَشْرَبَ الشَّرْبَةَ فَيَحْمَدَهُ عَلَيْهَا».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2734]
المزيــد ...
Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Dájúdájú Ọlọhun maa n yọnu si ẹrú ti o ba jẹun ti o wa dúpẹ́ lori rẹ, tabi ti o mu ti o wa dupẹ lórí rẹ”
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2734]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe idupẹ ẹrú fun Olúwa rẹ lórí ọla Rẹ ati awọn idẹra Rẹ wa ninu awọn alamọri ti maa n fa iyọnu Ọlọhun; ti o ba jẹun, o maa sọ pé: ALHAMDULILLAAH, ti o ba mu, o maa sọ pé: ALHAMDULILLAAH.