عن عائشة رضي الله عنها قالت: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«إنَّ المُؤْمِنَ ليُدرِكُ بِحُسْنِ خُلُقِهِ دَرَجَةَ الصَّائِمِ القَائِمِ».
[صحيح بشواهده] - [رواه أبو داود وأحمد] - [سنن أبي داود: 4798]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
“Dájúdájú pẹ̀lú iwa dáadáa, mumini maa de ipo aláàwẹ̀ ti n dide fun ìjọsìn ni oru”.
[O ni alaafia pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí rẹ] - [Abu Daud ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 4798]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe iwa rere maa mu ẹni tí n wù ú de ipo ẹni tí n dunni mọ́ aawẹ ni ọsan ati idide fun ìjọsìn ni oru, ohun ti o ko nǹkan ti n jẹ iwa rere sinu ni: Ṣíṣe dáadáa, ati ọrọ rere, ati ìtújúká, ati ki èèyàn ma fi suta kan ẹlòmíràn, ati fifi ara da suta lati ọdọ àwọn èèyàn.