عن عبد الله بن عمرو رضي الله عنهما قال:
لَمْ يَكُنِ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فَاحِشًا وَلَا مُتَفَحِّشًا، وَكَانَ يَقُولُ: «إِنَّ مِنْ خِيَارِكُمْ أَحْسَنَكُمْ أَخْلَاقًا».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 3559]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe:
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii se ọlọ́rọ̀ burúkú, kii sii mọ̀ọ́mọ̀ sọ ọrọ burúkú, o maa n sọ pe: “Dájúdájú ninu awọn ti wọn loore ju ninu yin ni àwọn tí ìwà wọn dára julọ”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3559]
Ko si ninu ìwà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki o maa sọ̀rọ̀ buruku, tabi wu iwa burúkú, kii sii mọ̀ọ́mọ̀ ṣe e, o si jẹ oníwà ńlá.
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ pe: Dajudaju ẹni tí ó ni ọlá jù ninu yin ni ọdọ Ọlọhun ni ẹni tí ìwà rẹ dara ju, pẹlu ṣíṣe dáadáa, ati ìtújúká, ati ki èèyàn ma fi suta kan ẹlòmíràn, ati fifi ara da suta lati ọdọ ẹlòmíràn, ati rírò pẹ̀lú àwọn èèyàn pẹ̀lú dáadáa.