+ -

عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«قَالَ اللهُ: أَنْفِقْ يَا ابْنَ آدَمَ أُنْفِقْ عَلَيْكَ».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé:
"c2">“Ọlọhun sọ pe: Maa na owó irẹ ọmọ Anọbi Adam, Ọlọhun maa fi òmíràn rọ́pò”.

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe Ọlọhun sọ pe: Irẹ ọmọ Adam, maa ná owó- ninu awọn ìnáwó ti o jẹ dandan ati eyi ti a fẹ́- maa gbòòrò arisiki rẹ, maa si fi òmíràn rọ́pò, maa si ba ọ fi alubarika si i.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣenilojukokoro lori saara ṣíṣe ati ninawo si oju ọna Ọlọhun.
  2. Ninawo sibi nnkan ti o loore wa ninu awọn okùnfà ìbùkún ti o tobi ju ninu arisiki ati ṣíṣe adipele rẹ, ati ki Ọlọhun fi òmíràn rọ́pò fun ẹrú.
  3. Hadiisi yii wa nínú ohun ti Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, gba wa lati ọdọ Oluwa rẹ, ati pe a n pe e ni Hadith Qudsiy tabi Hadith Ilaahiy, oun ni eyi ti gbólóhùn rẹ ati itumọ rẹ wa lati ọdọ Ọlọhun, sibẹsibẹ, ko ni awọn ìròyìn Al-Qur’an ti o ṣe iyatọ rẹ si ohunkohun miiran, gẹgẹ bii ìjọsìn pẹ̀lú kika rẹ, ati ṣíṣe imọra ti a ba fẹ kà á, ati ipenija, ati àìní ikapa lati mu irú rẹ wa, ati bẹẹ bẹẹ lọ.